Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Sept. 15
“Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa ń mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí tí wọ́n bá ń gbàdúrà. [Ka Mátíù 6:10.] Báwo lo rò pé ìgbésí ayé wa á ṣe rí bí a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìtumọ̀ apá kọ̀ọ̀kan nínú Àdúrà Olúwa, títí kan apá ibi tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yìí.”
Ile Ìṣọ́ Oct. 1
“Gbogbo wa là ń fẹ́ kí òpin dé bá ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn àti ogun. Ǹjẹ́ o rò pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí lè ṣẹ? [Ka Sáàmù 37:11. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí ìlérí yìí ṣe jẹ mọ́ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láti ṣe fún aráyé àti bá a ṣe lè nípìn-ín nínú ìbùkún yìí.”
Jí! Oct. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn nípa ìṣòro kan tó ń gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́, ìyẹn ni mímutí àmuyíràá. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 20:1.] Onírúurú ewu ló wà fáwọn ọ̀dọ́ tó ń mutí àmuyíràá. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa di onímukúmu.”
“Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun ìbànújẹ́ pé lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀dọ́mọbìnrin tí kò tíì lọ́kọ ló ń gboyún? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe nípa ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn ọ̀dọ́ abiyamọ. Ó tún ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sí ìṣòro yìí.” Ka 2 Tímótì 3:15.