Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Sept. 15
“Láyé òde òní, àwọn kan gbà pé àwọn ti há sínú ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́. Ibo ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti lè rí ìrànlọ́wọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì mú un dá wa lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́. [Ka Aísáyà 48:17, 18.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tó lè mú kí ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ lágbára sí i.”
Ilé Ìṣọ́ Oct. 1
“Ǹjẹ́ o tì í béèrè rí pé, ‘Bí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ èèyàn, tó sì jẹ́ pé òun lọba alágbára, kí nìdí tí kò fi yọ àwọn tó wà nínú ìpọ́njú kúrò nínú ìyà?’ [Jẹ́ kó fèsì.] Láìpẹ́ Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìṣòro kúrò. [Ka Aísáyà 65:17.] Ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé, ní báyìí ná, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ń wò wá nínú ìyà tó wá ṣe bí ẹni pé òun ò rí wa o.”
Jí! Oct. 8
“Ǹjẹ́ ó ti gbọ́ pé kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ mọ́ láti máa ṣíṣẹ àgbẹ̀ jẹun? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ tí nǹkan yóò dára. [Ka Sáàmù 72:16.] Nígbà tí mo bá padà wá, máa ṣàlàyé bí Ọlọ́run yóò ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.”