Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Sept. 1
“Ibo lo rò pé a ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nígbà tá a bá fẹ́ ṣàwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 3:5, 6.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bí ọgbọ́n tó ti òkè wá ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ká tó ṣèpinnu.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 8 hàn án.
Ile Iṣọ Oct. 1
“Lákòókò tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ yìí, ọ̀pọ̀ ló ń ṣàníyàn nípa bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti lẹ́mìí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. [Ka Aísáyà 65:17.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi yẹ ká lẹ́mìí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa lọ́jọ́ iwájú.”
Jí! July–Sept.
“Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni ìṣòro ìgbésí ayé ń bá fínra lọ́nà tó kàmàmà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 2 Tímótì 3:1.] Tó o bá mọ ẹnì kan tó sọ pé òun máa para òun kóun lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà àtàwọn ìṣòro ayé yìí, àwọn àlàyé tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí lè ràn án lọ́wọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.
“Èwo nínú àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí ni wà á fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀? [Ṣí ìwé ìròyìn náà sí ojú ìwé 24, kó o sì ka díẹ̀ lára àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀.] Ṣé Ọlọ́run wà? Báwo ni mó ṣe lè mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni mo sì ṣe lè ṣàlàyé pé ó wà lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 2 Tímótì 3:16.] Bó o bá ka àpilẹ̀kọ yìí, wà á rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o bá kà máa jẹ́ kó o mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò tíì mọ̀.”