Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Ohun Tó O Kọ́ ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” Sílò?
1 Ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe kọjá á rí i pé àwọn èèyàn Jèhófà ti múra tán láti ṣe iṣẹ́ olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a gbé lé wọn lọ́wọ́. (Mát. 28:19, 20) Bó o ṣe padà sílé, àwọn kókó pàtàkì wo nínú ìtọ́ni tó o gbà lo ti pinnu láti fi sílò nínú ìgbésí ayé rẹ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá?
2 Ìwé Mímọ́ Tí Ó Ní Ìmísí Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni: A gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kìíní ka 2 Tímótì 3:16. Lájorí àsọyé tí a gbọ́ ni: “A Ti Mú Wa Gbára Dì fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ó fi hàn pé ká tó lè gbára dì fún iṣẹ́ olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run a ní láti máa gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lárugẹ, ká máa gbé e gẹ̀gẹ̀ ju ìrònú èèyàn tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lọ, ká sì máa lò ó déédéé. A tún gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà lójoojúmọ́ fún ẹ̀mí mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká sì máa sapá láti mú èyí tó gba iwájú nínú èso ti ẹ̀mí dàgbà, ìyẹn ni ìfẹ́. Bákan náà, a ní láti jẹ́ kí ètò àjọ Jèhófà orí ilẹ̀ ayé kọ́ wa láti di òjíṣẹ́ nípasẹ̀ gbogbo ìpàdé ìjọ.
3 Àkòrí àpínsọ àsọyé ọjọ́ Friday ni “Bá A Ti Ń Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn, Ẹ Jẹ́ Ká Máa Kọ́ Ara Wa.” Àsọyé yìí ṣàlàyé pé a ní láti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ní ti (1) pípa àwọn òfin Ọlọ́run àti gbogbo ìlànà ìwà rere Kristẹni mọ́ (2) bíbá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ taápọntaápọn, àti (3) fífòpin sí àwọn ìwà àti ìrònú tí Èṣù lè yá lò láti fi ré wa lọ. Lẹ́yìn èyí, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tá a lè gbà láti dáàbò bo ìdílé wa kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè èyí tó ti di àjàkálẹ̀ àrùn nínú ayé. A rọ àwọn òbí láti fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa yíyẹra fún wíwo ìran oníwà pálapàla, ì báà jẹ́ fúngbà díẹ̀, kí wọ́n sì máa kíyè sí bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ohun tí wọ́n ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n. Èwo nínú àwọn kókó inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday lo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú lò?
4 Àsọyé tó gbẹ̀yìn ní ọjọ́ náà fún ìpinnu wa lókun láti mọyì ìmọ́lẹ̀ Jèhófà, láti sún mọ́ ẹgbẹ́ olóòótọ́ ti àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run dáadáa, ká sì máa gbé àlàáfíà lárugẹ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Ṣé o ti ka ìtẹ̀jáde tuntun náà tán, ìyẹn ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì?
5 A Tóótun Tẹ́rùntẹ́rùn Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn: Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kejì ni a fà yọ látinú 2 Tímótì 2:2. Bó o ṣe ń tẹ́tí sí àpínsọ àsọyé ní òwúrọ̀ Saturday, ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn tá a fún wa nípa bí a ṣe lè (1) wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, (2) padà lọ bẹ̀ wọ́n wò, àti bí a ṣe lè (3) kọ́ wọn láti ṣe gbogbo ohun tí Kristi pa láṣẹ? Ǹjẹ́ ò ń fi ohun tó o kọ́ sílò—ìyẹn ni pé kí o máa fi kókó kan látinú Ìwé Mímọ́, ó kéré tán, han àwọn onílé kí o sì máa ṣètò sílẹ̀ fún ìbẹ̀wò ọjọ́ iwájú?
6 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti fara wé Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Àwọn ọ̀nà wo lo gbà ń sapá láti lè túbọ̀ dà bíi rẹ̀? Látinú ohun tó o kọ́ nínú àpínsọ àsọyé kejì lọ́jọ́ náà, báwo lo ṣe rò pé o lè “Jàǹfààní Ní Kíkún Látinú Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ni”? Àwọn ìmọ̀ràn wo lo ti ń mú lò láti lè fi kún bó o ṣe ń pọkàn pọ̀ nígbà tó o bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tí ìpàdé ìjọ bá ń lọ lọ́wọ́?
7 Láìsí àní-àní, ìwé tá à ń retí náà, Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá sí i gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ń fi kọ́ni. A óò túbọ̀ pe àfiyèsí sí àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ ní àkókò tí a kọ Bíbélì ní. Ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà ní àwọn àpótí tó ń fi ohun tó yẹ ká ṣe, ìdí tó fi ṣe pàtàkì àti bá a ṣe lè ṣe é hàn, ní ṣókí. Àwọn ìfidánrawò tó gbéṣẹ́ wà nínú rẹ̀. Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n wà nínú ìwé náà fún àwọn arábìnrin, wọ́n sì lè yan èyíkéyìí nínú wọn láti fi ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. Bí àkókò ti ń lọ, a ó ṣe àwọn ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèfilọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ o ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó jíire fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìmúrasílẹ̀ kí o lè jàǹfààní ní kíkún látinú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
8 Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ Lójú Ìwòye Ibi Tí Àkókò Dé: Ìwé Hébérù 5:12 ló nasẹ̀ ohun tí àwọn tí wọ́n pé jọ máa gbádùn ní ọjọ́ Sunday. Àpínsọ àsọyé tí a sọ ní òwúrọ̀ Sunday, “Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì Múra Wa Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà,” rọ̀ wá láti fún Ọlọ́run ní ohun tó dára jù lọ lójú wa, ká sì kórìíra gbogbo onírúurú ìwà àdàkàdekè ká bàa lè la ọjọ́ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù Jèhófà já. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà,” fi hàn gbangba gbàǹgbà bí ẹ̀mí ìgbéraga, ìkánjú láti dé ipò ọlá, owú àti ìdúróṣinṣin èké tí Kórà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ní ṣe mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà fúnra rẹ̀. Àsọyé tó tẹ̀ lé e dá lórí i bí ó ti ṣe pàtàkì fún wa tó lónìí láti tẹrí ba fún ọlá àṣẹ nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Àwọn Wo Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ Gbogbo Orílẹ̀-Èdè?,” fẹ̀rí hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe èyí, kì í ṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù tó kàn ń fẹnu lásán sọ pé òun ń kọ́ni ní òtítọ́ Bíbélì.
9 Ó ṣe kedere pé, Jèhófà ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè di ọ̀dáńgájíá olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí a fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò, ká ‘máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wa kí a lè gba ara wa àti àwọn tí ń fetí sí wa là.’—1 Tím. 4:16.