“Ibo Ni Màá Ti Rí Àyè?”
1 Àròyé tí ọ̀pọ̀ wa máa ń ṣe nìyẹn nítorí ọwọ́ wa máa ń dí. Wọ́n sọ pé àkókò ló ṣe pàtàkì jù lọ tó sì máa ń tètè lọ mọ́ wa lọ́wọ́ jù lọ nínú gbogbo ohun tá a ní. Ibo la wá ti lè ráyè fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì ní tòótọ́, irú bíi kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?—Fílí. 1:10.
2 Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé a ní láti pinnu ohun tí a fẹ́ ṣe láàárín àkókò tí a ní, kì í ṣe pé ká gbìyànjú láti wá àkókò púpọ̀ sí i. Wákàtí méjìdínláàádọ́sàn-án [168] ni gbogbo wa ní lọ́sẹ̀, ó sì ṣeé ṣe ká lo ọgọ́rùn-ún lára rẹ̀ fún oorun sísùn àti iṣẹ́ ṣíṣe. Nígbà náà, báwo la ṣe lè lo wákàtí tó ṣẹ́ kù lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní jù lọ? Éfésù 5:15-17 dámọ̀ràn pé ká máa rìn “kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà . . . , ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” Èyí fi hàn pé ó yẹ láti máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti ṣe àwọn ohun tí Jèhófà sọ pé ó ṣe pàtàkì.
3 Jésù fi ọjọ́ wa wé ọjọ́ Nóà. (Lúùkù 17:26, 27) Ìgbòkègbodò ìgbésí ayé gba gbogbo àfiyèsí àwọn èèyàn nígbà náà lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n, Nóà wá àyè láti kan áàkì gìrìwò kan, ó sì wàásù. (Héb. 11:7; 2 Pét. 2:5) Báwo ló ṣe ráyè? Ó jẹ́ nípa fífi ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú àti nípa ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà “bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́n. 6:22.
4 Kí Ló Yẹ Kó Ṣáájú? Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń rí “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” gbà. (Lúùkù 12:42) Bí a óò bá jàǹfààní ní tòótọ́, ó ń béèrè dídá kàwé déédéé àti ṣíṣètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe déédéé láti mú kí gbogbo ẹ̀kọ́ náà wọni lọ́kàn. Nítorí ìmọrírì tá a ní fún oúnjẹ tẹ̀mí, a kì í kà á sí oúnjẹ ṣákálá kan, kí a kàn jẹ ẹ́ wọ̀mùwọ̀mù bí ìgbà téèyàn bá ń sáré jẹ oúnjẹ ti ara. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọrírì yíyẹ máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ká sì gbádùn àwọn ohun tẹ̀mí.
5 Jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí lè ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3) Ipò pàtàkì ló yẹ kí ó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa ojoojúmọ́. Ǹjẹ́ a lè wá àyè láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé Kristẹni? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí “èrè ńlá” gbà, èyí tó máa ń wá látinú mímọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti ṣíṣe é.—Sm. 19:7-11.