Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Nov. 15
“A ti gbọ́ táwọn èèyàn sọ pé ‘Jésù kú fún wa.’ [Fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jòhánù 3:16.] Ǹjẹ́ o tíì ṣe kàyéfì rí nípa bí ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè gba gbogbo wa là? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì pèsè ìdáhùn tó rọrùn. Àpilẹ̀kọ yìí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, ‘Jésù Ń Gbani Là—Lọ́nà Wo?,’ sì ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere.”
Ilé Ìṣọ́ Dec. 1
“Lákòókò yìí nínú ọdún, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń tẹra mọ́ fífúnni lẹ́bùn àti híhùwà inúure lóríṣiríṣi. Ìyẹn jẹ́ ká ronú nípa Òfin Pàtàkì Náà [Ka Mátíù 7:12.] Ǹjẹ́ o ronú pé ó ṣeé ṣe láti máa tẹ̀ lé òfin yẹn jálẹ̀ ọdún? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí pèsè ọ̀pọ̀ àlàyé tó ń gbádùn mọ́ni lórí kókó náà, ‘Òfin Pàtàkì Náà—Ǹjẹ́ Ó Ṣì Bóde Mu?’”
Jí! Dec. 8
“Bíbélì ṣèlérí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí kò ní sí ẹni tí yóò sọ pé ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ [Ka Aísáyà 33:24.] Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí yẹn, ìtẹ̀jáde Jí! yìí pe àfiyèsí sí irú àìsàn kan tó ń bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́mọdé lágbà fínra. A pe àkọlé rẹ̀ ní, ‘Ìrètí Ń Bẹ fún Àwọn Tí Oríkèé Ara Máa Ń Ro.’ Ó dá mi lójú pé wàá rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú rẹ̀.”