Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Dec. 15
“Lásìkò yìí nínú ọdún, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló máa ń ronú nípa Jésù Kristi, àtẹni tó lóun gbà á gbọ́ àtẹni tí ò gbà á gbọ́. Àwọn kan ní kì í ṣe ẹni gidi kan. Kí lèrò tìẹ ná? [Lẹ́yìn tí ẹni náà bá fèsì, ka Mátíù 16:15, 16.] Ó dá mí lójú pé wàá gbádùn kíka àpilẹ̀kọ yìí tó sọ̀rọ̀ nípa ‘Ẹni Náà Gan-an Tí A Ń Pè Ní Jésù,’ láti lè mọ bí ọ̀rọ̀ nípa Jésù ṣe kàn ọ́ lónìí àti bí yóò ṣe kàn ọ́ lọ́jọ́ iwájú.”
Jí! Jan. 8
Ǹjẹ́ o kò gbà pé ìgbésí ayé kò lè dẹrùn bí ominú bá ṣì ń kọ wá lórí bí a ṣe máa rí oúnjẹ ní ànító àti àníṣẹ́kù? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àkókò tí a kọ Bíbélì. [Ka Léfítíkù 26:4, 5.] Jí! sọ̀rọ̀ nípa àníyàn tó gbòde kan báyìí nípa ọ̀rọ̀ oúnjẹ. Ó tún sọ nípa àkókò tí Ọlọ́run yóò mú kí ìfọ̀kànbalẹ̀ wà kárí ayé.”
Ilé Ìṣọ́ Jan. 1
“O ha máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tó fi dà bíi pé àwọn èèyàn kan ń gbé ayé ìdẹ̀ra àmọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kí ọwọ́ wọ́n lè tó ẹnu? Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí. [Ka Jóòbù 34:19.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run yóò ṣe sọ ayé di ibi tí kò ti ní sí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ mọ́ tí gbogbo nǹkan á sì kárí lọ́gbọọgba.”
Jí! Jan. 8
“Gbogbo wa la ó ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó mi gbogbo ayé tìtì yìí. Látìgbà náà làwọn èèyàn ti nílò ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ tó bùáyà. Àpilẹ̀kọ yìí, ní pàtàkì, sọ ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe láti ran àwọn tí wọ́n yè bọ́ nínú jàǹbá náà lọ́wọ́, àti ohun tí wọ́n ń ṣe láti ran àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń ṣètọ́jú pàjáwìrì àti àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ́wọ́.”