Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Feb. 15
“Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣamọ̀nà ìgbésí ayé rẹ àti láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Díẹ̀ lára àwọn ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ, irú bí Òfin Pàtàkì náà, wà nínú Bíbélì. [Ka Mátíù 7:12.] Kí làwọn ìlànà Ọlọ́run mìíràn tó lè ṣe wá láǹfààní ní tààràtà? Wàá rí ìdáhùn nínú ìwé ìròyìn yìí.”
Jí! Mar. 8
“O lè ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ ni ó ti léwu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn yìí ní àwọn ìmọ̀ràn àtàtà lórí bí a ṣe lè mú kí wọ́n túbọ̀ láàbò sí i. Ó tún fi hàn pé ìlera ara wa sinmi lórí ojú tá a fi ń wo iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, bóyá a wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Jọ̀wọ́ kà á?”
Ilé Ìṣọ́ Mar. 1
“Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, ọ̀pọ̀ nínú wa ló ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nínú àdúrà kan tó gbajúmọ̀, Jésù Kristi sọ ìdí tí a fi lè wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. [Ka Mátíù 6:9, 10.] Ìran ènìyàn ń tún àwọn àṣìṣe tó ti ṣẹlẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ṣe. Àmọ́ láyé ìgbà yẹn, ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ jẹ́ ti àwọn tó sin Ọlọ́run. Ìwé ìròyìn yìí ń fi hàn bí irú ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe lè jẹ́ ti àwa náà.”
Jí! Mar. 8
“Bíbélì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ẹ̀kọ́ tó jíire. [Ka Òwe 22:10, 11.] Ọ̀pọ̀ nínú wa ló mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn ọmọ wa ní àwọn olùkọ́ tó tóótun. Ìwé ìròyìn Jí! sọ̀rọ̀ nípa ipa tó jọjú tí àwọn olùkọ́ ń kó, bó ṣe yẹ kí a fi ìmọrírì hàn fún yíyọ̀ọ̀da tí wọ́n ń yọ̀ọ̀da ara wọn, àti ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí kò rọrùn tó sì ń peni níjà tí wọ́n ń ṣe.”