A Óò Rí Àkànṣe Ìṣírí Gbà
1 Ọjọ́ kan ò lè lọ káwọn èèyàn Jèhófà máà rí àwọn ohun tó máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Níwọ̀n bí Èṣù ti mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ kíún ló kù fún òun, gbogbo agbára rẹ̀ ló fi ń ja ìjà àjàkẹ́yìn láti lè rí i pé òún ba ìwà títọ́ wa sí Jèhófà jẹ́. (Ìṣí. 12:12) Ó ṣe pàtàkì pé ká “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀” ká “bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí [a] bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí [a] sì lè dúró gbọn-in gbọn-in.”—Éfé. 6:10, 13.
2 Pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa jẹ́ ìṣètò kan látọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí agbára gbà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọrírì èyí. Ó máa ń wù ú láti wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ kí wọ́n bàa lè ‘jọ fún ara wọn ní ìṣírí,’ kí wọ́n sì “lè fìdí . . . múlẹ̀ gbọn-in.” (Róòmù 1:11, 12) Ká lè túbọ̀ ní okun láti ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣètò fún wa láti rí ìṣírí gbà ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tó ń bọ̀.
3 Wà Níbẹ̀ Kó O Lè Jàǹfààní: Ní in lọ́kàn pé o máa wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. A óò ‘ṣe ara wa láǹfààní’ tá a bá ti wà níbẹ̀ kí orin àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tá a sì dúró dìgbà tí a máa fi tọkàntọkàn ṣe “Àmín” sí àdúrà ìparí. (Aísá. 48:17, 18) Ọ̀pọ̀ ní láti ṣètò iṣẹ́ wọn tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò kí wọ́n bàa lè ráyè láti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ náà. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti ní kí ọ̀gá rẹ fún ọ láyè níbi iṣẹ́, àmọ́ Jèhófà ti fún wa ní ìdánilójú pé òún á ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 5:14, 15) Tí kò bá tí ì sí ètò gúnmọ́ kan ní ti ọkọ̀ tí a ó wọ̀ lọ, àti ibi tí a máa dé sí, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ kí á lọ ṣe bẹ́ẹ̀, ká má kàn sọ pé ọ̀rọ̀ á yanjú ara ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà á bù kún àwọn ìsapá wa láti wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.—Òwe 10:22.
4 Máa Wọ̀nà fún Ìṣírí Tó O Máa Rí Gbà: Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí, lẹ́yìn tí àpéjọ àgbègbè kan parí, kó o sọ pé: “Mi ò tíì gbádùn àpéjọ tó dùn tó báyìí rí!” Kí ló lè mú kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún rí bẹ́ẹ̀ lára rẹ? Ìdí ni pé, kì í pẹ́ rẹ̀ wá nítorí jíjẹ́ tí a jẹ́ aláìpé, ìyẹn la ṣe máa ń fẹ́ láti gba ìṣírí tẹ̀mí. (Aísá. 40:30) Arábìnrin kan sọ pé: “Ètò àwọn nǹkan yìí máa ń kó àárẹ̀ bá mi, àmọ́ àwọn àpéjọ àgbègbè máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti dá àfiyèsí mi padà sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó máa ń fún mi ní okun tẹ̀mí tí mo nílò. Ńṣe ló máa ń dà bíi pé àkókò tí mo nílò rẹ̀ gan-an ni ìṣírí náà máa ń dé sí.” Ó ṣeé ṣe kó ti ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ rí.
5 Kì í ṣe nínú àwọn àsọyé àtàwọn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò nìkan la ti máa ń rí ìṣírí tá a nílò gbà, a tún máa ń rí i gbà nínú àwọn apá alárinrin mìíràn nínú àpéjọ àgbègbè wa. Arákùnrin kan sọ pé: “Ohun tí èmi máa ń gbádùn jù lọ ni àwọn àlàyé tó ṣe kedere nípa bí a ṣe lè fi àwọn ìlànà wíwúlò tó wà nínú Bíbélì sílò. Ó dájú pé a ò lè kóyán àwòkẹ́kọ̀ọ́ kéré tá a bá ń sọ nípa jíjàǹfààní nínú àwọn àpẹẹrẹ tó ti kọjá, èyí tó dára àtèyí tó burú. Bákan náà, ara mi máa ń wà lọ́nà nígbà gbogbo de àwọn ìwé tuntun tó máa jáde, mo sì máa ń gbádùn wọn fún ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn tí mo bá ti padà sílé.”
6 Ìṣètò tó ṣe pàtàkì gan-an látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn àpéjọ àgbègbè wa jẹ́ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tím. 3:1) Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn onímìísí náà sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, ẹ di alágbára ńlá.” (1 Kọ́r. 16:13) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ká lè rí àkànṣe ìṣírí gbà ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run!” tí a bá yàn wá sí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ṣètò Kó O Lè Wà Níbẹ̀ ní Gbogbo Ọjọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta
■ Lọ tọrọ àyè lẹ́nu iṣẹ́.
■ Forúkọ sílẹ̀ fún ilé gbígbé ní ìpàdé àgbègbè.
■ Forúkọ sílẹ̀ fún mọ́tò tó o máa wọ̀ lọ sí ìpàdé àgbègbè.