Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ May 15
“Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe láti mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Wàá gbà pẹ̀lú mi pé ó ṣòro láti gbà gbọ́ nínú ẹnì kan téèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Ńṣe ni Bíbélì dìídì rọ̀ wá pé ká wá Ọlọ́run. [Ka Ìṣe 17:27.] Àwọn àpilẹ̀kọ yìí fi bí a ṣe lè túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáadáa hàn wá.”
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe kàyéfì pé, kí ló dé táwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ fi ń kú ikú òjijì. Ǹjẹ́ o ti ronú rí nípa ìdí tí àwọn èèyàn fi ń kú? [Jẹ́ kí ó fèsì, lẹ́yìn náà fi ṣáàtì tó wà ní ojú ewé 7 hàn án.] Ṣé wàá fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀kan lára àwọn èrò èké tó wọ́pọ̀ yìí?” Tó bá ṣeé ṣe, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a tọ́ka sí nínú ìwé ìròyìn náà.
Jí! June 8
“Oríṣiríṣi ètò làwọn aṣáájú ayé ti ṣe láti rí i pé àwọ́n bá wa yanjú àwọn ìṣòro wa. Ètò tuntun kan tí wọ́n tún ṣe báyìí la mọ̀ sí ètò sayé dọ̀kan. Nínú ìwé ìròyìn yìí, o lè kà nípa ọ̀nà tí akitiyan tuntun yìí ti lè gbà máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́. O tún lè kà nípa ojútùú kárí ayé kan tí Bíbélì ti sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà ka Mátíù 6:9, 10.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé sáyẹ́ǹsì àti ìsìn kò bára wọn rẹ́ rárá. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń wò ó pé kò ṣeé ṣe rárá kí ẹnì kan tí sáyẹ́ǹsì jẹ lọ́kàn gan-an ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Kí lèrò tìẹ lórí ọ̀ràn yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàlàyé kókó yìí lọ́nà tó máa yéni gan-an.”