Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ June 15
“Ǹjẹ́ o rò pé irú àwọn ìṣòro bí ìwọ̀nyí lè dópin láé? [Ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ máa tó dópin. [Ka Sáàmù 72:12-14.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run yóò ṣe ṣe èyí.”
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń lo ère nínú ìjọsìn wọn, nígbà tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn mìíràn sì rò pé èyí kò tọ̀nà. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú rí nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Jòhánù 4:24.] Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ṣàlàyé bí lílo ère nínú ìjọsìn ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ohun tí Bíbélì sọ nípa jíjọ́sìn ère.”
Jí! July 8
“Ǹjẹ́ o rò pé ó lè ṣeé ṣe kí gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé gbádùn òmìnira tòótọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Wo ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí. [Ka Róòmù 8:21.] Kí ìlérí yìí tó lè jẹ́ òtítọ́, àfi kí gbogbo ìfiniṣẹrú dópin, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ bí èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀.”
“Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn àkókò líle koko yóò wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. [Ka 2 Tímótì 3:1, 3.] Ìwà ipá tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i kárí ayé jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Ipò àwọn nǹkan ì bá mà burú jáì o ká ní kò sí àwọn ọlọ́pàá! Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣòro tí àwọn ọlọ́pàá ń kojú jákèjádò ayé.”