Ẹ Yè Kooro ní Èrò Inú bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
1 Léraléra ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ “bí olè,” ìyẹn ni pé ọjọ́ náà á kàn dé wẹ́rẹ́, lójijì, láìfi àkókò falẹ̀. (1 Tẹs. 5:2; Mát. 24:43; 2 Pét. 3:10; Ìṣí. 3:3; 16:15) “Ní tìtorí èyí,” Jésù sọ pé, “ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mát. 24:44) Báwo la ṣe lè máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí bí òpin ti ń sún mọ́lé? A lè rí ọ̀nà tá a lè gbà ṣe èyí nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run mí sí náà: “Ẹ yè kooro ní èrò inú.”—1 Pét. 4:7.
2 Láti jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, ó ṣe pàtàkì láti máa wo nǹkan lọ́nà tí Jèhófà ń gbà wò ó. (Éfé. 5:17) Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ara wa gẹ́gẹ́ bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (1 Pét. 2:11) Ó ń jẹ́ ká lè mòye àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì ní ti gidi, kí a fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ṣáájú, kí a sì ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.—Fílí. 1:10.
3 Gbé Góńgó Tẹ̀mí Kalẹ̀: Gbígbé góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ àti lílé wọn bá ń ràn wá lọ́wọ́ láti yè kooro ní èrò inú. Ǹjẹ́ o láwọn góńgó tẹ̀mí tó ò ń gbìyànjú láti lé bá? Ǹjẹ́ o máa ń sapá láti ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí o pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni, kí o ka ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kọ̀ọ̀kan tàbí bóyá kí o túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà? Bí o bá gbé àwọn góńgó tí kò ju agbára rẹ kalẹ̀, máa bá a nìṣó ní lílépa wọn, kí o sì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó bù kún ìsapá rẹ, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí àwọn àbájáde rẹ̀.
4 Alàgbà kan béèrè lọ́wọ́ tọkọtaya ọ̀dọ́ kan nípa góńgó tẹ̀mí tí wọ́n gbé kalẹ̀. Ìbéèrè náà mú kí wọ́n rí i pé bí wọn ò bá walé ayé máyà, tí wọ́n sì san gbèsè tó wà lọ́rùn wọn, wọ́n á lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. Wọ́n pinnu láti fi èyí ṣe góńgó wọn. Wọ́n sapá gidigidi láti san gbèsè náà, wọ́n sì dẹ́kun ṣíṣe àwọn nǹkan tí kò pọn dandan tó máa ń gba àkókò àti okun wọn. Nígbà tó pé ọdún kan géérégé lẹ́yìn náà, wọ́n ti lé góńgó wọn bá. Kí wá ni àbájáde èyí? Ọkọ náà sọ pé: “Ká ní kì í ṣe àwọn góńgó tá a gbé kalẹ̀ ni, à bá máà sí ní irú ipò tá a wà báyìí. A láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. A ò gbẹ́mìí ara wa sókè bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ayé wa sì túbọ̀ dáa si. Ó nítumọ̀, ó sì tún lárinrin.”
5 Bí a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, ǹjẹ́ kí a máa bá a nìṣó láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí nípa jíjẹ́ ẹni tó yè kooro ní èrò inú, kí a sì pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Títù 2:11-13.