Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ May 15
“Ojoojúmọ́ là ń gbọ́ ìròyìn nípa ìwà ipá. Ǹjẹ́ o rò pé irú ipò yẹn ti fìgbà kan wà rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [Ka Mátíù 24:37.] Ìwà ibi pọ̀ gan-an nígbà ayé Nóà débi pé Ọlọ́run pa gbogbo àwọn èèyàn náà run àyàfi Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló ṣẹ́ kù. Ìwé ìròyìn yìí fi bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ní ìtumọ̀ fún wa lónìí hàn.”
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Àwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ nípa àṣìlò owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ ń mú kí àwọn kan máa ṣe kàyéfì bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti máa dá owó fún àwọn ẹgbẹ́ aláàánú. Síbẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ló ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Kí lo rò pé a lè ṣe? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Hébérù 13:16.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé nípa irú ọrẹ tí inú Ọlọ́run dùn sí.”
Jí! June 8
“Lónìí, àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń ṣàkóbá fún ìlera wa. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ohun tá a lè ṣe wà láti dáàbò bo ara wa? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò nípa àwọn ohun wọ̀nyí, títí kan ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àkókò kan tí àìsàn ò ní sí mọ́.” Ka Aísáyà 33:24 láti fi parí ọ̀rọ̀ rẹ.
“Ó dà bí i pé ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn mọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé bó ṣe rí gan-an nìyẹn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé á rí bẹ́ẹ̀. [Ka 2 Tímótì 3:1-5.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò nípa ohun tó fà á tí ìlànà ẹ̀dá èèyàn fi ń yí padà àti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”