Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ June 15
“Àwọn kan gbà pé èèyàn ńlá ni Jésù pé kò sẹ́ni tó tó o nínú ìtàn. Àwọn mìíràn ò tiẹ̀ gbà pé ó wà rárá. Ǹjẹ́ o rò pé ohun tá a gbà gbọ́ nípa rẹ̀ ṣe pàtàkì? [Lẹ́yìn tó bá ti fèsì, ka Ìṣe 4:12.] Àwọn ẹ̀rí wo ló wà pé Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí rí? Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè yẹn.”
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ọ̀kan lára nǹkan tó jẹ àwa èèyàn lógún jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ká sì rẹ́ni nífẹ̀ẹ́ àwa náà. [Ka àkọlé àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4.] Síbẹ̀, ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé nǹkan míì làwọn èèyàn lóde ìwòyí fi sípò iwájú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun tí ojúlówó ìfẹ́ jẹ́ àti bí a ṣe lè ní in.” Ka 1 Kọ́ríńtì 13:2.
Jí! July 8
“Ìyọlẹ́nu gbáà ni ìwà ipá tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn. [Tọ́ka sí àpẹẹrẹ ìwà ipá kan táwọn èèyàn tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ yín mọ̀, kí o sì jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan tó máa ń sún àwọn èèyàn láti hùwà ọ̀daràn. Ó tún ṣàlàyé bí Ọlọ́run á ṣe mú ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kúrò pátápátá.” Ka Sáàmù 37:10, 11.