Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Apr. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ti kíyè sí i pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ le àwọn ìlànà ẹ̀sìn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Sáàmù 119:105.] Àwọn ìlànà ẹ̀sìn lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ìṣòro ìgbésí ayé. Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí ibi tí a ti lè rí ìlànà ẹ̀sìn tòótọ́.”
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Àwọn ìbéèrè kan kọjá agbára ẹ̀dá èèyàn láti dáhùn. Wo àpẹẹrẹ yìí. [Ka Jóòbù 21:7.] Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan tí o fẹ́ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àwọn èèyàn kárí ayé ṣe rí àwọn ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn sí mẹ́ta nínú àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.”
Jí! May 8
“Nínú ayé kóyákóyá tá à ń gbé lónìí yìí, àwọn kan ń wò ó pé ó dà bíi pé àwọn ọmọdé ń yára dàgbà ju bó ṣe yẹ lọ. Kí lèrò rẹ nípa èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Oníwàásù 3:1, 4.] Kò yẹ kí ìgbà ọmọdé jẹ́ àkókò tí àwọn ọmọdé á máa tẹ́rí gba iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò ọ̀nà tí àwọn òbí lè gbà mú kí àwọn ọmọ wọn gbádùn ìgbà èwe wọn.”
“Ọ̀pọ̀ lára wa ló mọ ẹnì kan tó ní àìsàn àtọ̀gbẹ. Ǹjẹ́ o mọ púpọ̀ nípa àìsàn yìí? [Fi iwájú ìwé ìròyìn náà han onílé, kí o sì jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn ohun tó ń fa àtọ̀gbẹ àti bí a ṣe lè tọ́jú rẹ̀. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Bíbélì pé ìwòsàn pípẹ́títí yóò wà fún gbogbo àìsàn.” Parí ìfilọni yìí nípa kíka Aísáyà 33:24.