Iṣẹ́ Tó Ń Tuni Lára
1 Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń tu gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbọ́ ọ, tí wọ́n sì ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wọn lára. (Sm. 19:7, 8) Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà eléwu, ó sì ń mú kí wọ́n ní ìrètí tó ṣeé gbára lé nípa ọjọ́ ọ̀la. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn tó ń tẹ́tí sí ìhìn rere náà nìkan ló máa jàǹfààní. Àwọn tó ń sọ òtítọ́ inú Bíbélì tó ń tuni lára fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ń rí ìtura gbà.—Òwe 11:25.
2 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà Fún Wọn Lókun: Jésù sọ pé àwọn tó bá gba àjàgà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, yóò “rí ìtura fún ọkàn [wọn].” (Mát. 11:29) Jésù fúnra rẹ̀ rí i pé wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn ń fúnni lókun. Bí oúnjẹ ni iṣẹ́ náà rí fún un. (Jòh. 4:34) Nígbà tó rán àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn láti lọ wàásù, inú wọn dùn láti rí bí Jèhófà ṣe ń tì wọ́n lẹ́yìn.—Lúùkù 10:17.
3 Bákan náà, kíkópa tí ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lónìí ń fún wọn lókun. Arábìnrin kan sọ pé: ‘Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń tù mí lára nítorí pé ó ń jẹ́ kí ayé mi lójú, kí ó sì nítumọ̀. Ńṣe làwọn ìṣòro tí mò ń bá yí àti wàhálà ojoojúmọ́ máa ń dín kù nígbà tí mo bá jáde òde ẹ̀rí.’ Òjíṣẹ́ mìíràn tó jẹ́ onítara sọ pé: ‘Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń jẹ́ kí n máa rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni gidi lójoojúmọ́, kí n sì ní àlàáfíà àti ayọ̀ inú lọ́hùn-ún tí n kò lè rí lọ́nà mìíràn.’ Àǹfààní ńlá gbáà mà ló jẹ́ o, láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”!—1 Kọ́r. 3:9.
4 Àjàgà Kristi Jẹ́ Ti Inú Rere: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù gba àwa Kristẹni níyànjú láti “tiraka tokuntokun,” ohun tó ní ká ṣe kò ju agbára wa lọ. (Lúùkù 13:24) Ńṣe ló ń ké sí wa tìfẹ́tìfẹ́ láti bọ́ sábẹ́ àjàgà pẹ̀lú òun. (Mát. 11:29) Kí ó dá àwọn tó wà nínú ipò líle koko lójú pé inú Ọlọ́run dùn sí iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe tọkàntọkàn, bí wọn ò tiẹ̀ lè ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ ọ̀hún.—Máàkù 14:6-8; Kól. 3:23.
5 Ó mà ń tuni lára o, láti máa sin Ọlọ́run tó mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe nítorí orúkọ rẹ̀! (Héb. 6:10) Ǹjẹ́ kí a máa sakun nígbà gbogbo láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe.