Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
Lóde òní, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni ló wà nípa bá a ṣe lè mú kí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ká bàa lè túbọ̀ gbádùn ayé wa, kí ẹ̀mí wa sì lè gùn sí i. Àmọ́, èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni ipò tí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa wà. Nípa báyìí, ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe wa tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní February 2004 bá a mu gan-an ni. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni: “Fífi Ọkàn-Àyà Pípé Pérépéré Sin Jèhófà.” (1 Kíró. 28:9) Àwọn ohun wo la óò kọ́?
Alábòójútó àyíká yóò jíròrò kókó náà, “Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Fi Inú Dídùn Sin Jèhófà.” Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí a ó ṣe yóò jẹ́ ká mọ ayọ̀ tó ń wá látinú mímú kí ìfẹ́ àwọn tó fẹ́ láti sin Jèhófà jinlẹ̀ sí i àti èyí tó ń wá látinú bíbá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò sí àní-àní pé gbogbo àwọn tó máa wá sí àpéjọ yìí yóò rí ìtùnú àti ìṣírí gbà látinú àsọyé àkọ́kọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò sọ, ìyẹn ni: “Dídáàbò Bo Ọkàn Wa Nínú Ayé Onídààmú Yìí.” Ọ̀rọ̀ ìrìbọmi ni yóò mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ wá sópin.
Lọ́sàn-án, àsọyé náà, “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́,” yóò jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Kí làwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo ọkàn-àyà àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè nípa búburú lórí wọn, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà? Àsọyé náà, “Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Fẹ́ràn Jèhófà,” yóò fún wa láwọn àbá tó gbéṣẹ́, yóò sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe èyí.
Ǹjẹ́ à ń lo gbogbo àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè láti mú kí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa? Àsọyé tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò sọ gbẹ̀yìn ni: “Máa Fi Ọkàn-àyà Pípé Pérépéré Sin Jèhófà.” Yóò sọ̀rọ̀ lórí apá pàtàkì mẹ́rin nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tí à ń ṣe déédéé, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Báwo ni àkókò tá à ń yà sọ́tọ̀ àti ipá tá à ń sà nínú gbígba àdúrà àtọkànwá, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wíwàásù tìtara-tìtara àti bíbá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́ ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú sí i nínú ṣíṣe èyíkéyìí lára àwọn nǹkan yìí?
Jèhófà ń ké sí wa pé: “Mú ọkàn-àyà rẹ wá fún ìbáwí àti etí rẹ fún àwọn àsọjáde ìmọ̀.” (Òwe 23:12) Bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ láti ìsinsìnyí lọ láti wá sí àpéjọ ọlọ́jọ́ kan yìí níbi tí a ó ti gbọ́ ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́ tó lè ṣàǹfààní fún wa. Ṣíṣe èyí yóò fún ọ lókun láti máa bá a nìṣó ní fífi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sin Jèhófà.