Orin Tí Ń Mára Tuni
1 Orin ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn tòótọ́. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ásáfù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ kọrin pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà. . . . Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin atunilára sí i, ẹ máa fi gbogbo àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀ ṣe ìdàníyàn yín.” (1 Kíró. 16:8, 9) Lóde òní, a máa ń kọrin sí Jèhófà ní àwọn ìpàdé ìjọ wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Éfé. 5:19) Àǹfààní ńláǹlà mà lèyí o láti yin orúkọ rẹ̀!—Sm. 69:30.
2 Bí a bá ń fetí sí orin Kingdom Melodies, ìyẹn àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tí àwọn ará kọ, ó lè mú ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Arábìnrin kan sọ pé: “Bí mo bá ti ń gbọ́ orin amáratuni wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni mo máa ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Ọ̀nà dáradára mà lèyí o láti máa ronú nípa Jèhófà bí mo ṣe ń gbádùn orin!”—Fílí. 4:8.
3 Àwọn Ìgbà Tá A Lè Gbádùn Wọn: Gbígbọ́ orin Kingdom Melodies nílé ń mú kí ilé tura, kí nǹkan tẹ̀mí sì máa wà lọ́kàn àwọn aráalé, èyí tó máa ń mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé. Ìdílé kan kọ̀wé pé: “A máa ń gbọ́ [orin] yìí gan-an nílé àti nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, kì í sì í sú wa torí pé orin adùnyùngbà ni. Orin Kingdom Melodies sábà máa ń jẹ́ kí ara wa balẹ̀ nígbà tá a bá ń múra láti lọ sí ìpàdé ìjọ tàbí tá a bá ń lọ sí àpéjọ.” Arábìnrin kan sọ pé: “Wọ́n máa ń mú kí ara mi túbọ̀ yá gágá nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ilé, àbí ta ló lè rò pé màá máa yọ̀ níbi tí mo ti ń káṣọ? Mo máa ń gbọ́ orin yìí nígbà tí gbogbo nǹkan bá sú mi. Orin náà ń mórí ẹni yá gágá! . . . Kò sí èyí tí kì í fún mi láyọ̀ nínú gbogbo ẹ̀.” Ǹjẹ́ ó láwọn ìgbà tí àwọn orin amáratuni yìí lè ṣe ìwọ náà láǹfààní?
4 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orin tí wọ́n ń ṣe jáde lónìí ló ń gbé ẹ̀mí ayé lárugẹ. Àwọn òbí lè mú kí àwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn orin tó bójú mu nípa lílo orin Kingdom Melodies dáadáa. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àtàwọn olùfìfẹ́hàn ni inú wọn yóò dùn láti mọ̀ nípa àwọn orin adùnyùngbà wọ̀nyí, tí ń yin Jèhófà lógo tó sì ń mára yá gágá.—Sm. 47:1, 2, 6, 7.