Ìgbòkègbodò Àkànṣe Láti Mú Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Tọ Àwọn Èèyàn Lọ
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà lóde ìwòyí tó jẹ́ pé báyé ṣe ń lọ ò dùn mọ́ wọn. Àmọ́, ìwọ̀nba kéréje làwọn tó mọ ìdí ẹ̀ táyé fi rí bó ṣe rí yìí, ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n bàa lè la ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀ já. (Ìsík. 9:4) Ká bàa lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó, ìgbòkègbodò àkànṣe yóò wáyé láti mú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, tọ àwọn èèyàn lọ. Èyí yóò bẹ̀rẹ̀ láti Monday, March 21 títí di Sunday, April 17.
2 A lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, nígbà ìpadàbẹ̀wò, nígbà tá a bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, tàbí nígbà tá a bá báwọn èèyàn pàdé lójú pópó tàbí lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Àmọ́, ìyẹn ò wá sọ pé ká máa kó ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! lé àwọn èèyàn lọ́wọ́ yàlàyàlà o. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ni ká fún. Bá a bá rí àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a lè fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú.
3 Bó o bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ ẹnì kan lọ́kàn, o lè sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro líle koko àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń jáni láyà èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ lákòókò tá a wà yìí. [Fún un ní àpẹẹrẹ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì ti sọ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ á ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó bá àpẹẹrẹ tó o fún un mu. O lè ka Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:7, 10, 11; tàbí 2 Tímótì 3:1-5.] Bíbélì jẹ́ kí ìtumọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí ye wa. Ó sì tún sọ àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan náà? [Jẹ́ kó fèsì. Fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà bó bá fìfẹ́ hàn.] Ńṣe là ń fún àwọn èèyàn ní ìwé pẹlẹbẹ náà láì díye lé e. Bó o bá fẹ́ fi owó díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé, inú wa yóò dùn láti gbà á.”
4 O sì lè rí i pé á dára jù kó o gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀ lọ́nà yìí:
◼ “Nǹkan ò fara rọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn láyé tá a wà yìí nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń já wọn láyà tàbí nítorí ohun búburú jáì tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé kí ló kúkú ṣe tí Ọlọ́run ò dá sí wa kó sì bá wa kòòré àwọn láburú tó ń ṣẹlẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa tó bá aráyé fòpin sí ìjìyà. Nínú ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ kà yìí, ṣàkíyèsí oore tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. [Ka Sáàmù 37:10, 11.] Ṣé wàá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i?” Lo ìparí ọ̀rọ̀ tá a dábàá ní ìpínrọ̀ kẹrin.
5 Rí i dájú pé o kọ orúkọ àti àdírẹ́sì gbogbo àwọn tó bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà sílẹ̀, kó o sì wá bó o ṣe máa padà lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ síwájú sí i. Àwọn àbá nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ máa jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2005. Bí ẹnì kan bá fi ìfẹ́ hàn gan-an nígbà tó o bá kọ́kọ́ ṣe ìpadàbẹ̀wò síbẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ẹsẹ. O lè lo ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! tàbí ìwé mìíràn bí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti bẹ̀rẹ̀ irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀.
6 Wàá rí ìwé pẹlẹbẹ yìí gbà lẹ́yìn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí a óò ti jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. A dámọ̀ràn pé káwọn akéde àtàwọn aṣáájú ọ̀nà kọ́kọ́ gba ìwọ̀nba ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n bá máa lò lóde ẹ̀rí ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tá a bá bẹ̀rẹ̀. Ǹjẹ́ kí Jèhófà fìbùkún rẹ̀ sórí ìgbòkègbodò àkànṣe yìí kó lè yọrí sí ìyìn rẹ̀ káwọn tó fi tọkàntọkàn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ níbi gbogbo sì lè jàǹfààní látinú ẹ̀.—Sm. 90:17.