Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Sept. 15
“Gbogbo èèyàn tó ń gbé lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé ló ti gbọ́ nípa Jésù Kristi. Àwọn kan sọ pé gbogbo ohun táwọn mọ̀ nípa rẹ̀ ò ju pé ó jẹ́ ẹni àrà ọ̀tọ̀ lọ. Àwọn míì sì ń sìn ín gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Olódùmarè. Irú èèyàn wo lo rò pé Jésù Kristi jẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé irú ẹni tó jẹ́ gan-an, ibi tó ti wá, àti ibi tó wà báyìí.” Ka Jòhánù 17:3.
Ile Iṣọ Oct. 1
Ka ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn náà. Kó o wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ o mọ àmì tí ibi yìí ń tọ́ka sí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Mátíù 24:3.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàyẹ̀wò márùn-ún tọ̀ọ̀tọ̀ lára àwọn àmì náà, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká mọ̀ wọ́n.” Fi àpótí tó wà lójú ìwé 6 hàn án.
Jí Oct. 8
“Àìmọye ìṣòro ló ń tìdí àmujù ọtí wá. O lè kà nípa ìpalára tí ọtí ń ṣe fún ara nínú ìwé ìròyìn yìí. [Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 7.] Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé báwọn èèyàn ṣe lè ṣíwọ́ nínú àmujù ọtí àti ọ̀nà táwọn ẹlòmíràn lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́.”
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ríbi tó bójú mu gbé. Ǹjẹ́ o rò pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ilé tó pọ̀ tó á wà fún gbogbo èèyàn láti máa gbé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Jí! máa ń gbé ìròyìn tó bágbà mu jáde nípa ìṣòro ilé gbígbé. Ó tún ń jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run á mú ìlérí rẹ̀ nípa ilé gbígbé ṣẹ.” Ka Aísáyà 65:21, 22.