Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Bíbéèrè Ìbéèrè àti Fífetísílẹ̀
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbádùn sísọ èrò wọn ṣùgbọ́n wọn kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa kọ́ àwọn bí ọmọdé tàbí kó máa fi ìbéèrè lọ́ àwọn nífun. Nítorí náà, àwa Kristẹni tá a jẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ mọ ọ̀nà tá a ó gbà láti máa jẹ́ kí àwọn èèyàn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.—Òwe 20:5.
2 Ṣe làwọn ìbéèrè tá a bá bi àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ sún wọn láti ronú jinlẹ̀, kò yẹ kó kàn wọ́n lábùkù. Nígbà tí arákùnrin kan ń wàásù láti ilé dé ilé, ó bi onílé pé: “Ṣó o rò pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á máa yẹ́ ara wọn sí tí wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn?” Lẹ́yìn tẹ́ni yẹn ti fèsì, ó tún béèrè pé: “Kí lo rò pé ó máa jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe?” tàbí “Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?” Nígbà tí arákùnrin mìíràn ń wàásù láìjẹ́ bí àṣà àti láwọn ibi térò sábà máa ń pọ̀ sí, ó bi àwọn òbí pé: “Gẹ́gẹ́ bí òbí, àǹfààní wo lẹ rò pó wà nínú kéèyàn jẹ́ abiyamọ?” Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá béèrè pé: “Kí ni ẹ máa ń ṣàníyàn lé lórí jù?” Ṣàkíyèsí pé àwọn ìbéèrè yìí mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sọ èrò wọn láìsí pé a kàn wọ́n lábùkù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipò àwọn èèyàn yàtọ̀, a lè mú kí kókó tá à ń jíròrò àti ohùn tá a fi ń béèrè ìbéèrè bá àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu.
3 Mímú Káwọn Èèyàn Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn: Báwọn èèyàn bá ń sọ èrò wọn jáde, fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, má sì gé ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. (Ják. 1:19) Yìn wọ́n fún ohun tí wọ́n bá sọ. (Kól. 4:6) O kàn lè sọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn yín.” Bí wọ́n bá sọ ohun tó yẹ kó o tìtorí rẹ̀ yìn wọ́n, dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn tọkàntọkàn. Fi sùúrù bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó lè jẹ́ kó o mọ ohun tí wọ́n ń rò àti ohun tó jẹ́ kí wọ́n rò bẹ́ẹ̀. Wá ibi térò yín ti jọra. Bó o bá fẹ́ kí wọ́n ka Ìwé Mímọ́, ó lè sọ pé: “Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé èyí lè ṣeé ṣe?” Ṣọ́ra fún ríranrí mọ́ èrò tìẹ nìkan, má sì ṣe máa jiyàn.—2 Tím. 2:24, 25.
4 Bá a ṣe ń fetí sílẹ̀ á ṣe púpọ̀ nínú báwọn èèyàn á ṣe máa fèsì ìbéèrè tá a bá bi wọ́n. Àwọn èèyàn á mọ̀ bá a bá ń fọkàn bá ọ̀rọ̀ wọn lọ. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Bó o bá fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló máa ṣe nínú jíjẹ́ kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o fi lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ò ń ro tàwọn mọ́ tìẹ.” Fífetí sáwọn èèyàn ń buyì kún wọn ó sì lè sún wọn láti fetí sí ìhìn rere tá a fẹ́ sọ fún wọn.—Róòmù 12:10.