Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ June 15
“Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé lásìkò tá a wà yìí, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ń fúnra wọn pinnu ohun tó dáa àtèyí tí ò dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpẹẹrẹ kan rèé nípa ìtọ́ni tó bá àkókò mu látinú Bíbélì. [Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan látinú àpótí tó wà lójú ìwé 6 àti 7.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àǹfààní tá a máa rí bá a bá ń fi àwọn ìwà rere tí Bíbélì mẹ́nu bà ṣèwà hù.”
Ile Iṣọ July 1
“Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ṣe kàyéfì nípa báwọn èèyàn ṣe máa ń fojú ẹ̀dá bíi tiwọn gbolẹ̀ torí pé ẹ̀yà tiwọn yàtọ̀ tàbí torí pé ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá tàbí torí pé wọ́n ń sọ èdè tó yàtọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ bí Bíbélì ṣe sọ ohun tó fà á. [Ka 1 Jòhánù 4:20.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí gbogbo ẹ̀yà wà níṣọ̀kan?
Jí! Apr.–June
“Ǹjẹ́ o rò pé agbára àìrí kan wà tó ń fa àwọn ìṣòro tó ń da ayé yìí láàmú? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù mú kó di mímọ̀ pé Sátánì ni eku ẹdá tó ń dá gbogbo ìṣòro tó wà nínú ayé lónìí sílẹ̀. Ohun tó ti pinnu láti máa ṣe rèé. [Ka Ìṣípayá 12:9.] Ó ṣe pàtàkì ká gbà pé Sátánì wà, ká sì yáa fi ara wa pa mọ́ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ewé 24 hàn án.
“Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wù pé káwọn ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, káwọn má sì fi ara àwọn wọ́lẹ̀ ti wá ń kojú ìṣòro báyìí. Ìṣòro ọ̀hún ò sì ṣẹ̀yìn pípè tí wọ́n ń pè wọ́n láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó burú nínú ìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ṣàlàyé 1 Kọ́ríńtì 6:9 fún un.] Béèyàn bá máa ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí, àfi kéèyàn yáa kọ̀ jálẹ̀ kó máà lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ewé 14 hàn án.