Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Di Akéde Ìjọba Ọlọ́run
1 Àṣẹ tí Jésù pa fàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Mátíù 28:19, 20 kò mọ sákòókò wọn. Ó pàṣẹ fún wọn láti sọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i dọmọ ẹ̀yìn, káwọn tí wọ́n sọ dọmọ ẹ̀yìn náà sì tún máa sọ àwọn ẹlòmíì dọmọ ẹ̀yìn. Wọ́n á lè tipa bẹ́ẹ̀ fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún àṣekágbá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó máa kárí ayé, lákòókò pàtàkì tá a wà yìí, ìyẹn àkókò òpin.—Mát. 24:14.
2 Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè jẹ́ àwọn ọmọ wa tàbí àwọn ẹlòmíì tó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A fẹ́ ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́wọ́ látọkàn wa wá, kí wọ́n lè mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi.—Lúùkù 6:40.
3 Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Wàásù: Fún àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣìírí láti sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tó o ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fún wọn. Kọ́ àwọn ọmọ rẹ bí wọ́n ṣe lè wàásù lọ́nà tó nítumọ̀ láti kékeré níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn. (Sm. 148:12, 13) Fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ pé o ò kóyán iṣẹ́ ìwàásù kéré.—1 Tím. 1:12.
4 Kìkì àwọn tó fara mọ́ ìlànà òdodo Ọlọ́run tí wọ́n sì fi ń ṣèwà hù nìkan ni Jèhófà máa ń lò. Lóòótọ́, àwọn akéde tuntun ò ní ìmọ̀ tó àwọn tó ti nírìírí, tó ti yara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ gba àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì fi kọ́ni gbọ́, kí wọ́n sì ṣe tán láti ṣàlàyé wọn fáwọn ẹlòmíì. (Wo ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 79 sí 82.) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú “Bábílónì Ńlá,” tí wọ́n sì ti jáwọ́ nínú ìṣèlú, wọ́n gbọ́dọ̀ máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé.— Ìṣí. 18:2, 4; Jòh. 17:16; Héb. 10:24, 25.
5 Bó o bá ti rí i pé ọ̀kan lára àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti kúnjú ìwọ̀n láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, tètè sọ fún alága àwọn alábòójútó. Alága àwọn alábòójútó á wá ṣètò pé káwọn alàgbà méjì jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìwọ àti ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè pinnu bóyá ó tóótun láti máa jáde pẹ̀lú ìjọ fún iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba tí kò tíì ṣèrìbọmi. Èyí á fún ẹ láǹfààní síwájú sí i láti túbọ̀ kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ nǹkan bẹ́ ẹ ti jọ ń kẹ́sẹ̀ rìn lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.