Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
Kí la lè ṣe táwọn tó ń ta ko ìjọsìn tòótọ́ lójú méjèèjì ò fi ní rí wa gbéṣe? Ọgbọ́n wo la lè ta sí i tá a fi máa lékè àwọn tí Sátánì ń lò láti sọ wá dà bó ṣe dà? Àpéjọ Àyíká ti ọdún iṣẹ́ ìsìn 2009 la ti máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì yìí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi.” (Róòmù 12:21) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn nǹkan tó wà nípamọ́ fún wa yẹ̀ wò.
Èyí làwọn àsọyé tí alábòójútó agbègbè máa sọ, “Jèhófà Ń Fún Wa Lágbára Láti Lè Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi,” “Má Ṣe Dá Ara Rẹ Lójú Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ!,” “Gbogbo Ìwà Ibi Máa Tó Dópin!,” àti “Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Wa Lókun Ká Lè Ṣẹ́gun Ayé.” Alábòójútó àyíká máa sọ àwọn àsọyé tó ní àkòrí náà “Ìsinsìnyí Gan-an Ló Yẹ Ká Jí Lójú Oorun!” Róòmù 13:11-13 la gbé èyí kà. Ó tún máa sọ àsọyé náà, “Má Rẹ̀wẹ̀sì Nígbà Tíṣòro Bá Dé,” a gbé èyí ka Òwe 24:10. À ń fojú sọ́nà fún apá ti alábòójútó àyíká tún máa bójú tó, ìyẹn “Àwọn Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó ní Àyíká.” Apá tó tún máa fún wa níṣìírí ni, “Ṣó O Lè “Wà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Yìí” Nípa Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà?” Àkòrí àkọ́kọ́ lára àpínsọ àsọyé tá a máa gbọ́ ni “Ẹ Dúró Gbọn-in Lòdì Sáwọn Ètekéte Èṣù.” Àsọyé yìí máa jẹ́ ká dá àwọn ètekéte Èṣù mọ̀, ó sì máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè yàgò fún wọn, nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, eré ìnàjú àti nínú ẹ̀kọ́ ìwé. Àpínsọ àsọyé kejì tó ní àkòrí náà “Gba Agbára Tí Wàá Fi Ṣẹ́gun Sátánì Láwọn Ọjọ́ Burúkú Yìí,” máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè túbọ̀ lo ìmọ̀ràn onímìísí tó wà nínú Éfésù 6:10-18 lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
Ṣíṣẹ́gun ibi láti ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tan mọ́ra wọn ní tààràtà. (Ìṣí. 12:17) Abájọ tí kò fi sú Sátánì láti máa gbéjà ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà! (Aísá. 43:10, 12) Àmọ́, ó dájú pé Èṣù máa pòfo kẹ́yìn ni, tórí a ti pinnu láti “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” Nítorí náà, pinnu láti jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú apá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.