Àpéjọ Àyíká Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà
Jèhófà ló yẹ ká fògo fún. Ọ̀nà wo la lè gbà fògo fún Jèhófà? Kí ló mú kó ṣòro fáwọn kan láti máa fògo fún un? Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó ń fògo fún un? Ní Àpéjọ Àyíká tọdún 2008 la ó ti rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè yìí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára ìtọ́ni tí ń gbéni ró, tá a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tá a máa rí gbà ní àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì náà.
Alábòójútó àgbègbè á sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó bíi “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fògo fún Ọlọ́run?” àti “Máa Fàpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Nínú Pípa Àṣẹ Ọlọ́run Mọ́.” Òun náà ni yóò sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ á jẹ́, “Àwọn Wo Ló Ń Fògo fún Ọlọ́run?” àti ọ̀rọ̀ àsọparí tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ á jẹ́, “Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Jùmọ̀ Ń Fògo fún Un Jákèjádò Ayé.” Bákan náà ni yóò darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àsọyé tí alábòójútó àyíká máa sọ á dá lórí àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ bíi, “Jẹ́ Kí Gbígbé Ògo Ọlọ́run Yọ Máa Fún Ọ Láyọ̀,” “Àwọn Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó ní Àyíká” àti “Ẹ ‘Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in Gbọn-in Nínú Òtítọ́,’” èyí tó dá lórí 2 Pétérù 1:12. Láfikún sí i, a máa gbọ́rọ̀ tó dá lórí kókó náà, “Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Fògo fún Ọlọ́run.” Àkọ́kọ́ lára àpínsọ àsọyé méjì tó máa múni ronú jinlẹ̀, èyí tá a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní “Bá A Ṣe Lè Máa Fi Gbogbo Apá Ìgbésí Ayé Wa Yin Jèhófà Lógo,” máa ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:31. Àpínsọ àsọyé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Láti Fi Yin Jèhófà” máa tú pẹrẹ́pẹrẹ̀ nípa onírúurú ọ̀nà tá a gbà ń sin Ọlọ́run. Ọjọ́ Sunday la máa gbádùn àkópọ̀ Ilé Ìṣọ́ àti ìjíròrò ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́. Àǹfààní sì tún máa wà láti ṣèrìbọmi fáwọn tó bá tóótun.
Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ni wọ́n kọ̀ láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ìgbòkègbodò ẹ̀dá ló gba ọ̀pọ̀ wọn lọ́kàn débi tí wọn ò fi ráyè ronú nípa ọlá ńlá Jèhófà. (Jòh. 5:44) Ṣùgbọ́n ní tiwa, ó dá wa lójú pé kò sóhun tó ṣe pàtàkì tó lílo àkókò wa láti fi jíròrò kókó ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run.” Ṣètò láti rí i pé o wà ní àpéjọ yìí kó o bàa lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lọ́jọ́ méjèèjì tí àpéjọ yìí á fi wáyé.