Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Dec. 1
“Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé èrò àwọn èèyàn nípa ìmọ́tótó yàtọ̀ síra? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tí ìmọ́tótó fi ṣe pàtàkì. [Ka 1 Pétérù 1:16.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ohun tá a lè ṣe ká lè máa wà ní mímọ́ tónítóní.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 9 hàn án.
Ilé Ìṣó Jan. 1
“Èrò táwọn èèyàn jákèjádò ayé ní nípa Màríà ìyá Jésù yàtọ̀ síra. Kí lèrò tìẹ nípa Màríà? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì fi hàn pé Màríà jẹ́ ẹni pàtàkì nínú ìtàn. [Ka Lúùkù 1:30-32.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ohun tá a lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀.”
Jí Jan.–Mar.
“Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ronú lórí ìbéèrè yìí. [Tọ́ka sí ìbéèrè tó wà níwájú ìwé.] Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ìdí tá a fi lè sọ pé kì í ṣe níní àwọn ohun tówó lè rà nìkan ló fi hàn pé ayé yẹni. [Ka Jòhánù 17:3.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí.”
“Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ẹni tó lókìkí, ọlá tàbí agbára ni ayé yẹ. Ta lo lè sọ pé ayé yẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ó ń mú kí ayé yẹni. [Ka Sáàmù 1:1-3.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun mẹ́fà tó lè mú kí ayé yẹni. Sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 6.”