Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
1. Kí nìdí tá a fi ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, báwo la sì ṣe lè máa gbádùn ẹ̀ dáadáa?
1 A ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kó lè mú wa gbára dì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó méso jáde. Ohun tó dá lé lórí ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, sísọni dí ọmọ ẹ̀yìn àti pípolongo ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń sún mọ́lé. (Mát. 28:20; Máàkù 13:10; 2 Pét. 3:7) Ìgbà tá a bá múra ìpàdé pàtàkì yìí sílẹ̀ tá a sì tún múra tán láti kópa la máa gbádùn ẹ̀ jù lọ.
2. Báwo la ṣe lè múra àsọyé tá a máa gbọ́ sílẹ̀?
2 Àsọyé: A máa ń sọ ibi tẹ́ni tó máa bójú tó apá yìí ti máa mú ọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ìtọ́ni fún olùbánisọ̀rọ̀. O lè ṣàyẹ̀wò ibi tí wọ́n ti máa mú ọ̀rọ̀ jáde, kó o ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀, kó o sì ronú lórí bó o ṣe lè lo ìsọfúnni náà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.
3. Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn?
3 Ìbéèrè àti Ìdáhùn: Bá a ṣe ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ la ṣe ń darí apá yìí, ó máa ń ní ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí àti ọ̀rọ̀ ìkádìí. Fàlà sáwọn kókó pàtàkì tó wà ní ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì múra láti dáhùn ní ṣókí, kó sì nítumọ̀.
4. Báwo la ṣe lè múra apá tó jẹ́ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ sílẹ̀?
4 Ìjíròrò Pẹ̀lú Àwùjọ: Bí àsọyé la ṣe máa ń bójú tó apá yìí, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹni tó ń bójú tó o máa ń pe àwùjọ láti kópa. Tó o bá fàlà sáwọn kókó pàtàkì, tó o sì ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀, wàá lè dáhùn nígbà tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè. Arákùnrin tó ń bójú tó apá yìí máa rí i pé òun pe àwùjọ kí wọ́n lè fa àwọn kókó pàtàkì yọ.
5. Kí ló máa jẹ́ ká jàǹfààní tó pọ̀ látinú àwọn àṣefihàn?
5 Àṣefihàn: Àwọn iṣẹ́ kan máa ń ní àṣefihàn nínú, láti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè lo ohun tá a jíròrò náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. A máa ń lo alàgbà, àkéde tó nírìírí tàbí aṣáájú-ọ̀nà láti ṣe àwọn àṣefihàn yìí. Ọ̀nà tó o lè gbà múra sílẹ̀ fún apá yìí ni pé, kó o máa ronú lórí bí wọ́n ṣe máa gbé àṣefihàn náà kalẹ̀. Tí wọ́n bá ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a tẹ̀ sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ronú lórí bó o ṣe lè sọ ọ̀rọ̀ náà di tara ẹ àti bó o ṣe lè gbé e kálẹ̀ lọ́dọ̀ onírúurú èèyàn. Máa rí i dájú pé o mú ìtẹ̀jáde tàbí ìwé ìròyìn tí wọ́n máa fi ṣàṣefihàn náà wá sípàdé. Ó tún lè ṣe yín láǹfààní tẹ́ ẹ bá fi àwọn kan lára àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà dánra wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín.
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn?
6 A máa ń gbádùn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a bá múra ẹ̀ sílẹ̀, tá a sì ń fojú sọ́nà fún àwọn ìtọ́ni tá a máa rí gbà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè máa fún ara wa níṣìírí. (Róòmù 1:11, 12) Tá a bá ń wáyè láti múra Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sílẹ̀, a máa dẹni tó gbára dì láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́.—2 Tím. 3:17.