ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/10 ojú ìwé 2
  • Ìtọ́ni fún Àwọn Tó Ń Ṣiṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtọ́ni fún Àwọn Tó Ń Ṣiṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 9/10 ojú ìwé 2

Ìtọ́ni fún Àwọn Tó Ń Ṣiṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí, a fẹ́ mú àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń lò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn rọrùn sí i. A fẹ́ fi àwọn ìtọ́ni àti ìránnilétí tá a fẹ́ mẹ́nu bà yìí kún ìtọ́ni tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù May 2009, lábẹ́ àpilẹ̀kọ náà, “Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.” Èyí á mú kí àwọn ìtọ́ni náà túbọ̀ ṣe kedere.

◼ Àsọyé: Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tààràtà tí àwùjọ kò ní dá sí. Kí ẹ mú un látinú ibi tá a bá yàn. Kí olùbánisọ̀rọ̀ tẹnu mọ́ àwọn ohun tó bá máa ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ.

◼ Ìbéèrè àti Ìdáhùn: Bíi ti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, apá yìí máa ń ní ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀ ṣókí, a sì máa ń béèrè ìbéèrè lórí gbogbo ìpínrọ̀ tó bá wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Kí ẹni tó bá bójú tó apá yìí má ṣe sọ̀rọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ẹ lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹnu mọ́ ohun tá à ń jíròrò bí àkókò bá ṣe wà sí. Ẹ má ṣe ka àwọn ìpínrọ̀ àyàfi tá a bá ní kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀.

◼ Ìjíròrò: Èyí jẹ́ àsọyé tí àwùjọ máa lóhùn sí. Kò ní jẹ́ àsọyé látòkèdélẹ̀, gbogbo rẹ̀ kò sì ní jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn.

◼ Àṣefihàn àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò: Bí ìtọ́ni bá sọ pé kẹ́ ẹ ṣe àṣefihàn, ó túmọ̀ sí pé arákùnrin tó ni iṣẹ́ yẹn ní láti ṣètò fún àṣefihàn, kò túmọ̀ sí pé òun fúnra rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ ṣe àṣefihàn náà. Àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere ni kó yàn láti ṣe àṣefihàn náà. Tó bá ṣeé ṣe, kí arákùnrin náà ti ṣe ètò tó yẹ pẹ̀lú wọn kó tó di ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe àṣefihàn náà. Ohun tó máa dáa jù ni pé kí ẹ má ṣe máa lo àwọn akéde tuntun àtàwọn akéde tí kò tíì ní ìrírí láti ṣe àṣefihàn bó ṣe yẹ ká máa wàásù torí pé ẹ fẹ́ kí wọ́n ṣáà lè láǹfààní láti gun orí pèpéle. Àmọ́, ẹ lè fi àwọn akéde tuntun kan ṣe onílé. Kí àwọn akéde tó bá ń ṣe àṣefihàn má ṣe kọ ẹ̀yìn sí àwùjọ. Àwọn tẹ́ ẹ bá fẹ́ fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu wọn ní láti wá sí orí pèpéle, kí wọ́n má ṣe sọ̀rọ̀ láti orí ìjókòó wọn. Ẹ fi àwọn àṣefihàn àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò dánra wò ṣáájú àkókò. Bí àkókò bá ti lọ, tí arákùnrin kan sì ní láti dín iye ìṣẹ́jú tó máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀ kù, kó má ṣe yọ àṣefihàn àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kúrò nínú iṣẹ́ náà. Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó yan ẹni tí wọ́n bá fẹ́ lò fún àṣefihàn tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, kí wọ́n máa fi tó olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tàbí alàgbà míì létí.

Kí ẹ máa fara balẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá a bá dìídì fún yín lórí àwọn iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí ẹ bá ń fi àwọn ìtọ́ni yìí sọ́kàn nígbà tẹ́ ẹ bá níṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, èyí á mú kẹ́ ẹ lè kó ipa tiyín láti mú kí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn wáyé “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́