Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí la lè ṣe láti máa rí i pé àwọn ìpàdé ìjọ kò kọjá àkókò?
Tá a bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ ọ̀rọ̀ tó dùn mọ́ wa, ká tó mọ̀ àkókò á ti lọ. Ìdí rèé tó fi lè ṣòro láti parí apá tí à ń bójú tó ní ìpàdé láàárín àkókò tí a yàn fún un. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa parí ìpàdé lákòókò?
Ẹ bẹ̀rẹ̀ lákòókò. Nígbà tí ìjọ bá pé jọ fún ìpàdé, yóò dára pé ní nǹkan bí ìṣẹ́jú kan tàbí méjì kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ ká ti sọ fún àwùjọ pé kí wọ́n lọ jókòó sórí ìjókòó wọn ká bàa lè bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lákòókò bó ṣe yẹ. (Oníw. 3:1) Ní ti àwọn ìpàdé tó jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ló máa ń wá síbẹ̀, irú bíi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ká má ṣe máa dúró de àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n pẹ́ dé ká tó bẹ̀rẹ̀.
Múra sílẹ̀ dáadáa. Ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká má máa kọjá àkókò ni ìmúrasílẹ̀. Fi ẹ̀kọ́ pàtàkì tí iṣẹ́ rẹ fẹ́ kọ́ àwọn ará sọ́kàn. Mọ àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀, àwọn ni kí o sì tẹnu mọ́. Má jẹ́ kí àwọn kókó tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gbà ọ́ lákòókò. Gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀ lọ́nà tí yóò rọrùn láti lóye. Tí apá tí ò ń bójú tó bá ní àṣefihàn tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nínú, ẹ fi í dánra wò ṣáájú. Gbìyànjú láti máa fi aago díwọ̀n àkókò tó gbà ọ́ láti sọ̀rọ̀ rẹ nígbà tó o bá ń fi í dánra wò.
Pín ọ̀rọ̀ rẹ kéékèèké. Yálà ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ àsọyé tàbí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, yóò ṣe ọ́ láǹfààní tó o bá pín in kéékèèké. Pinnu ìwọ̀n àkókò tí wàá lò lórí ìpín kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ ọ́ sí etí ìwé rẹ. Wá rí i dájú pé ò ń ṣọ́ àkókò tí ò ń lò lórí ìpín kọ̀ọ̀kan nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ ní ìpàdé. Nígbà tó o bá ń jíròrò pẹ̀lú àwùjọ, yẹra fún ọ̀fìn gbígba ìdáhùn tó pọ̀ jù níbẹ̀rẹ̀ tí wàá fi wá máa kánjú jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà níwájú. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fi àkókò tó pọ̀ tó sílẹ̀ láti jíròrò àpótí àtúnyẹ̀wò níparí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí wọ́n kíyè sára kí wọ́n má bàa lo àkókò orin àti ti àdúrà ìparí mọ́ ti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ o.
Ẹ máa parí ìpàdé lákòókò. Nínú ìpàdé tó ní apá púpọ̀ bíi Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, olùbánisọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ní láti fi ìgbà tí apá tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àti ìgbà tí yóò parí sọ́kàn. Kí la lè ṣe nígbà tí ìpàdé bá fẹ́ kọjá àkókò? Ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn arákùnrin tó máa bójú tó apá yòókù lè dín àkókò tó yẹ kí wọ́n lò kù nípa pípọkànpọ̀ sórí àwọn kókó tó ṣe pàtàkì jù kí wọ́n sì fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sílẹ̀. Mímọ báa ti ń ṣe èyí la fi ń dá olùkọ́ tó dáńtọ́ mọ̀.
Àwa tá a wà láwùjọ lè ran arákùnrin tó ń darí ìpàdé lọ́wọ́ nípa jíjẹ́ kí ìdáhùn wa ṣe ṣókí kó sì mú kókó jáde. Nítorí náà gbogbo wa la lè ṣèrànwọ́ láti rí i pé à ń ṣe àwọn ìpàdé “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.