ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 51 ojú ìwé 263-ojú ìwé 264 ìpínrọ̀ 4
  • Lo Àkókò Tó Ṣe Rẹ́gí, Pín Àkókò Bó Ṣe Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Àkókò Tó Ṣe Rẹ́gí, Pín Àkókò Bó Ṣe Yẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 51 ojú ìwé 263-ojú ìwé 264 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 51

Lo Àkókò Tó Ṣe Rẹ́gí, Pín Àkókò Bó Ṣe Yẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ńṣe ni kí o sọ̀rọ̀ rẹ parí ní àkókò tí a yàn fún ọ, kí o sì pín àkókò tí a yàn fún iṣẹ́ rẹ sórí apá kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ yẹn bó ṣe yẹ.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ó yẹ kí o pín àkókò tí ó tó fún kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí ìtọ́ni rẹ dá lé lórí. Ó ṣe pàtàkì pé kí ìpàdé parí lákòókò.

ÒÓTỌ́ ni pé ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni kí ọ̀nà ìgbàkọ́ni rẹ dára, síbẹ̀ dídíwọ̀n àkókò ọ̀rọ̀ rẹ náà yẹ fún àfiyèsí. Àwọn ìpàdé wa ní àkókò tó yẹ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àti àkókò tó yẹ kí wọ́n parí. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, ó gba ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo ẹni tó bá máa kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn.

Láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì, ojú táwọn èèyàn ìgbà yẹn fi ń wo ìgbésí ayé yàtọ̀ sí ojú tí àwọn èèyàn fi ń wò ó ní ọ̀pọ̀ ibi lóde òní. Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ tí kò sọ agogo géérégé láti fi sọ àkókò. Bí àpẹẹrẹ wọ́n lè sọ pé, “nǹkan bí wákàtí kẹta” tàbí “nǹkan bí wákàtí kẹwàá.” (Mát. 20:3-6; Jòh. 1:39) Wọn kì í sábàá janpata nípa wákàtí àti ìṣẹ́jú géérégé tí ìgbòkègbodò ẹni lójúmọ́ bọ́ sí. Láwọn apá ibì kan láyé òde òní, ojú kan náà yìí ni wọ́n fi ń wo àkókò.

Wàyí o, ì báà jẹ́ àṣà àdúgbò tàbí wíwọ̀ tó wọ̀ fún wọn ló fà á tí àwọn kan kì í fi í janpata nípa àkókò, a ṣì lè jàǹfààní bí a bá mọ bí a ṣe lè fún un láfiyèsí tó yẹ. Nígbà tó bá di pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìwọ̀n àkókò tí a bá yàn fún apá kọ̀ọ̀kan. Ìlànà tó sọ pé “kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò” dára gan-an láti lò nípa ọ̀ràn títẹ̀lé àkókò tí a yàn fún iṣẹ́ wa nípàdé.—1 Kọ́r. 14:40.

Béèyàn Ṣe Lè Máa Tẹ̀ Lé Àkókò Iṣẹ́ Ẹni. Ìmúrasílẹ̀ loògùn rẹ̀. Bí olùbánisọ̀rọ̀ kò bá tẹ̀ lé àkókò, ohun tó sábà máa ń fà á ni pé ìmúrasílẹ̀ rẹ̀ kò tó. Ó lè jẹ́ pé ó dá ara rẹ̀ lójú jù. Tàbí kí ó má tètè múra iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ títí tí àkókò tí ó máa sọ ọ́ á fi wọnú. Títẹ̀lé àkókò bó ṣe yẹ gba pé kí o kọ́kọ́ mọrírì iṣẹ́ tí a yàn fún ọ, kí o sì tún fẹ́ láti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa.

Ṣé iṣẹ́ ìwé kíkà la yàn fún ọ? Kọ́kọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ 4 sí 7, tó dá lórí yíyọ̀mọ́nilẹ́nu-ọ̀rọ̀, dídánudúró, títẹnumọ́-ọ̀rọ̀, àti títẹnumọ́ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀. Wá mú ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn lò bí o ṣe ń ka ìwé tí a fún ọ sókè. Díwọ̀n àkókò tí o lò. Ṣé ohun tó ń béèrè ni pé kí o sáré kà á kí ó tó lè parí lákòókò tí a yàn fún ọ? Nígbà náà, ka àwọn ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lọ́nà tó túbọ̀ yá díẹ̀, ṣùgbọ́n máa bá a lọ láti máa dánu dúró kí o sì máa rọra ka àwọn ibi tí kókó pàtàkì wà láti lè tẹnu mọ́ wọn. Máa fi dánra wò lemọ́lemọ́. Bó bá ṣe túbọ̀ ń yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu sí i, ni yóò máa rọrùn fún ọ láti ṣàtúnṣe lórí àkókò tí ò ń lò láti fi kà á.

Ṣé àkọsílẹ̀ ìránnilétí lo fẹ́ lò láti fi sọ̀rọ̀ ni? Kò nílò kíkọ àkọsílẹ̀ jàn-ànràn janran, bóyá kí ó wá dà bí pé ńṣe lo fẹ́ kà á, kí o tó lè tẹ̀ lé àkókò bó ṣe yẹ. Nígbà tí ò ń ṣiṣẹ́ lórí Ẹ̀kọ́ 25, o kọ́ ọ̀nà tó dára láti gbà ṣe é. Rántí àwọn kókó márùn-ún wọ̀nyí: (1) Múra ìsọfúnni tó dára sílẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kó pọ̀ jù. (2) Jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ ṣe kedere lọ́kàn rẹ, ṣùgbọ́n má ṣe há odidi gbólóhùn ibẹ̀ sórí. (3) Kọ iye àkókò tó o fẹ́ lò fún apá kọ̀ọ̀kan tàbí iye àkókò tó yẹ kó o lò tí wàá fi dórí àwọn kókó kan, sínú ìlapa èrò rẹ. (4) Nígbà tí o bá ń múra sílẹ̀, ronú nípa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tó o lè fò tó bá di pé àkókò kò fẹ́ tó ọ mọ́. (5) Fi bí o ṣe máa sọ̀rọ̀ rẹ dánra wò.

Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn fi iṣẹ́ ẹni dánra wò. Bí o ṣe ń fi iṣẹ́ rẹ dánra wò, máa kíyè sí àkókò tí a yàn fún ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Fi iṣẹ́ rẹ dánra wò léraléra títí tí wàá fi lè sọ ọ́ láàárín àkókò tí a yàn fún un. Má ṣe gbìyànjú láti kó ìsọfúnni tó pọ̀ jù sínú ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ. Ṣẹ́ àkókò díẹ̀ kù nítorí pé àkókò tí o máa fi sọ ọ̀rọ̀ rẹ níwájú àwùjọ lè gùn ju èyí tó o máa fi sọ ọ́ nígbà ìdánrawò rẹ ní ìdákọ́ńkọ́.

Pípín Àkókò Tó O Máa Lò fún Apá Kọ̀ọ̀kan. Títẹ̀lé àkókò bó ṣe yẹ wé mọ́ pípín àkókò tó o máa lò láti fi sọ apá kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ náà. Àárín ọ̀rọ̀ ló yẹ kí o ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò náà. Ibẹ̀ ni àwọn kókó pàtàkì ìtọ́ni tí ò ń fúnni wà. Ó yẹ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ gùn tó èyí tí wàá fi lè rí àwọn nǹkan mẹ́ta tí a mẹ́nu kàn ní Ẹ̀kọ́ 38 ṣe. Kò yẹ kí àárín ọ̀rọ̀ gùn jàn-ànràn débi tí kò fi ní sí àkókò tó láti fi sọ ìparí ọ̀rọ̀ lọ́nà tó múná dóko gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ẹ̀kọ́ 39.

Akitiyan rẹ láti rí i pé o lo àkókò bó ṣe yẹ yóò mú kí ọ̀rọ̀ rẹ sunwọ̀n sí i yóò sì tún fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn yòókù tó ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn àti gbogbo ìjọ pẹ̀lú.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Múra sílẹ̀ dáadáa, kí o sì tètè ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú àkókò.

  • Yan àkókò fún apá kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ bó ṣe yẹ, kí o sì tẹ̀ lé àkókò yẹn.

  • Fi bó o ṣe máa sọ̀rọ̀ dánra wò.

ÌDÁNRAWÒ: Ṣètò láti dé ìpàdé ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú ṣáájú kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, ṣe èyí nípa yíyan àkókò tí ìwọ àti ìdílé rẹ yóò lò láti fi múra kí ẹ sì gbéra ìpàdé. Má gbàgbé láti fi àkókò tí ẹ ó fi rìn dé ọ̀hún kún un o. Ronú nípa bí o ṣe máa borí àwọn ìṣòro tó lè mú kí ẹ pẹ́ dé ìpàdé. Gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìṣètò rẹ yìí léraléra, kí o máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Irú ìlànà kan náà yìí ni kí o lò nígbà tí o bá níṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́