Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ October 1
“Ọ̀pọ̀ lónìí ni kò gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà. Kí lo rò pé ó fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ohun kan tó ṣeé ṣe kó fà á. [Ka Hábákúkù 1:2, 3.] Àpilẹ̀kọ yìí dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn kan sábà máa ń béèrè nípa Ọlọ́run, èyí tó mú kí wọ́n má ṣe gbà á gbọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 11 hàn án.
Jí! October–December
“Ikú òbí ẹni máa ń dunni gan-an. Ṣé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí ti tu ọ̀pọ̀ èèyàn nínú. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé béèyàn ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tí òbí ẹni bá kú, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn ní ṣọ́ọ̀ṣì ló wà nínú Bíbélì? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ní ká ṣọ́ra kí wọ́n má bàa fi ẹ̀kọ́ èké tàn wá jẹ. [Ka Kólósè 2:8.] Ìwé ìròyìn yìí tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké mẹ́fà tó ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”
Jí! October–December
“Ṣé ìṣòro tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí fínra le ju tàwọn ọ̀dọ́ àtijọ́ lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ bá àkókò tá a wà yìí mu gan-an. [Ka 2 Tímótì 3:1.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn àbá tó gbéṣẹ́ tó lè mú káwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ kojú ìṣòro yìí kí wọ́n sì kẹ́sẹ járí.”