Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ December 1
“Ǹjẹ́ o gbà pé ìṣòro tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ ń dojú kọ pọ̀ gan-an ju ti àwọn tọkọtaya lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò fún àwọn tó ń dójú kọ ìṣòro. [Ka Sáàmù 41:1.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 22 ṣàlàyé bá a ṣe lè máa fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ.”
Ji! January–March
“Ojú táwọn kan fi ń wo Ọlọ́run ni pé kì í ṣe ẹni gidi kan. Àwọn míì sì gbà pé ó máa ń ní ìmọ̀lára. Kí ni èrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí. [Ka 1 Pétérù 5:6, 7.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 19 jẹ́ ká mọ àlàyé tí Bíbélì ṣe lórí ìbéèrè yìí, Ṣé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run?”
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìtàn àròsọ lásán ni ìtàn ọgbà Édẹ́nì jẹ́. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jésù sọ pé Ádámù àti Éfà gbé láyé lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Mátíù 19:4-6.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa ọgbà Édẹ́nì.”
Ji! January–March
“Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe ọdún Kérésì ní December 25, nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù? [Jẹ́ kó fèsì.] Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, kò lè jẹ́ àkókò òtútù ni wọ́n bí Jésù. [Ka Lúùkù 2:8.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ bí àwọn kan lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ ọdún Kérésì ṣe bẹ̀rẹ̀.”