Ọ̀nà Tó Dára Láti Gbádùn Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbà pé orin jẹ́ ẹ̀bùn tó dára láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ják. 1:17) Ọ̀pọ̀ ìjọ ló máa ń gbádùn àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tó máa ń lọ lábẹ́lẹ̀, kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Orin Ìjọba Ọlọ́run máa ń mú kí ara tù wá bá a ṣe ń dé sí ìpàdé. Ó máa ń múra ọkàn wa sílẹ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run. Síwájú sí i, bá a ṣe máa ń gbọ́ àwọn orin tuntun tó wà nínú ìwé orin wa yìí máa ń jẹ́ ká mọ ohùn àwọn orin náà dáadáa, ó sì tún máa ń jẹ́ ká lè kọ àwọn orin náà bó ṣe tọ́. Bá a ṣe ń gbọ́ àwọn orin yìí lẹ́yìn ìpàdé máa ń jẹ́ kí ara tù wá bá a ṣe ń gbádùn ìfararora tó ń gbéni ró. Nitorí náà, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ètò tó yẹ nípa bí ohùn orin, ìyẹn Sing to Jehovah—Piano Accompaniment á ṣe máa lọ lábẹ́lẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé. Kí wọ́n rí i dájú pé orin náà kò lọ sókè jù débi pé àwọn ará kò ní lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá ara wọn sọ.