ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/12 ojú ìwé 1
  • Ìdí Méjìlá Tá A Fi Ń Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Méjìlá Tá A Fi Ń Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Jẹ́ Ká Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Máa Fi Ìtara Wàásù Nìṣó
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí o Tẹ́wọ́ Gbà Nínú Olúwa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 6/12 ojú ìwé 1

Ìdí Méjìlá Tá A Fi Ń Wàásù

Kí nìdí tá a fi ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn tá a sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ǹjẹ́ ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè? (Mát. 7:14) Ìyẹn ni ìdí àkọ́kọ́ lára ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí, àmọ́ òun kọ́ ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ. Èwo ni ìwọ kà sí pàtàkì jù lára ìdí méjìlá yìí tó mú ká máa wàásù tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

1. À ń gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là.—Jòh. 17:3.

2. À ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn burúkú.—Ìsík. 3:18, 19.

3. Ó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ.—Mát. 24:14

4. Ó ń fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ olódodo. Nígbà tí Jèhófà bá pa àwọn èèyàn burúkú rùn, kò sẹ́ni tó lè dá Jèhófà lẹ́bi pé kò fún wọn láyè láti ronú pìwà dà.—Ìṣe 17:30, 31; 1 Tím. 2:3, 4.

5. Ó ń jẹ́ ká lè san gbèsè tá a jẹ́, ìyẹn láti ṣèrànwọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀jẹ̀ Jésù rà.—Róòmù 1:14, 15.

6. Ó ń gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—Ìṣe 20:26, 27.

7. Ó jẹ́ ohun tó pọn dandan kí àwa fúnra wa lè rí ìgbàlà.—Ìsík. 3:19; Róòmù 10:9, 10.

8. Ó ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.—Mát. 22:39.

9. Ó fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—Mát. 28:19, 20.

10. Ó jẹ́ ara ìjọsìn wa.—Héb. 13:15.

11. Ó ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—1 Jòh. 5:3.

12. Ó ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́.—Aís. 43:10-12; Mát. 6:9.

Ó ṣe kedere pé kì í ṣe torí àwọn ìdí yìí nìkan la ṣe ń wàásù. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, ó sì máa ń fún wa láǹfààní láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 3:9) Ṣùgbọ́n, ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń wàásù ni ìdí kejìlá [12]. Bóyá àwọn èèyàn fetí sí wa tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, ó sì ń jẹ́ kí Jèhófà lè fún ẹni tó ń ṣáátá rẹ̀ lésì. (Òwe 27:11) Ó dájú pé a ní ọ̀pọ̀ ìdí tó ṣe pàtàkì tó fi yẹ ká máa “bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere.”—Ìṣe 5:42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́