ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/12 ojú ìwé 2
  • Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tó O Bá Ń Rò Pé O Kò Tóótun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tó O Bá Ń Rò Pé O Kò Tóótun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìwọ Náà Lè Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • O Lè Di Olùkọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Máa Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Fi Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Àfojúsùn Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 11/12 ojú ìwé 2

Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tó O Bá Ń Rò Pé O Kò Tóótun

1. Kí nìdí tí kì í yá àwọn akéde kan lára láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn?

1 Ǹjẹ́ o máa ń rò pé o kò tóótun láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kó yá àwọn akéde kan lára láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn. Nígbà àtijọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi Mósè àti Jeremáyà náà rò pé àwọn kò tóótun láti jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn. (Ẹ́kís. 3:10,11; 4:10; Jer. 1:4-6) Èyí fi hàn pé irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í ṣe nǹkan tuntun. Kí lo wá lè ṣe láti borí ìṣòro yìí?

2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mọ sórí ìwàásù ilé-dé-ilé nìkan?

2 Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kò ní gbé iṣẹ́ tó ju agbára wa lọ fún wa. (Sm. 103:14) Torí náà, iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ pé ká máa “sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn,” ká sì “máa kọ́ wọn” kì í ṣe iṣẹ́ tó ju agbára wa lọ. (Mát. 28:19, 20) Gbogbo wa pátá ni Jèhófà fún láǹfààní yìí, kì í ṣe àwọn tó nírìírí tó pọ̀ tàbí àwọn ẹ̀bùn àbínibí kan. (1  Kọ́r. 1:26, 27) Torí náà, kò yẹ ká fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mọ sórí ìwàásù ilé-dé-ilé nìkan. Ká wá máa ronú pé ojúṣe àwọn akéde kan ni láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú ká tóótun láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

3 Jèhófà Ló Ń Mú Ká Tóótun: Jèhófà ló ń mú ká tóótun láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (2  Kọ́r. 3:5) Ó lo ètò rẹ̀ láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ táwọn tó ní ìmọ̀ nínú ayé pàápàá kò tiẹ̀ mọ̀ rárá. (1  Kọ́r. 2:7, 8) Ó jẹ́ ká mọ bí Jésù tó jẹ́ olùkọ́ ńlá náà ṣe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ní onírúurú ọ̀nà, ká lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ó sì tún ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ìjọ wa. Bákan náà, Jèhófà pèsè àwọn ìwé tá a lè fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà tó rọrùn tó sì lè tètè yéni. Gbogbo èyí mú kó rọrùn fún wa láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

4. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́?

4 Jèhófà ran Mósè àti Jeremáyà lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó rán wọn. (Ẹ́kís. 4:11, 12; Jer. 1:7,  8) Àwa náà lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó ṣe tán, ohun tó dára lójú Ọlọ́run là ń ṣe bá a ṣe ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa rẹ̀. (1 Jòh. 3:22) Torí náà, pinnu pé wàá máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí pé èrè àti àǹfààní púpọ̀ wà níbẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́