“Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni”
Oṣooṣù la máa ń fi apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn bójú tó bá a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn wa lọni. Kì í ṣe pé a fẹ́ máa fi apá yìí ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wa o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àbá tá a lè lò láti fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni la retí pé ká fi jíròrò. Nítorí náà, kí arákùnrin tẹ́ ẹ bá yan apá yìí fún tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kó jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ṣókí, kó sì mú kí àwọn ará nífẹ̀ẹ́ sí ohùn tó wà nínú àwọn ìwé náà. Lẹ́yìn náà, kó yan àpilẹ̀kọ (tàbí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ) kan, kó sì ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe lè lò ó. Kó máa yan àwọn àpilẹ̀kọ tó bá fẹ́ jíròrò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, kí àwùjọ lè máa fọkàn bá a lọ̀, kí wọ́n sì lè mọ àwọn àbá tí wọ́n lè lò. Dípò kí ẹnì kan sọ ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan látòkè délẹ̀, ṣe ni kí ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àwùjọ sọ oríṣiríṣi ìbéèrè tí wọ́n lè fi mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà kí àwọn ará sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Kó wá ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé ìròyìn náà lọni. A rọ̀ wá pé ká máa ka àwọn ìwé ìròyìn náà wá láti ilé, ká sì múra sílẹ̀ láti sọ bá a ṣe lè lò ó. Tí gbogbo wa bá ń múra apá yìí sílẹ̀ dáadáa, a ó lè máa fi ran ara wa lọ́wọ́ bí irin ṣe máa ń pọ́n irin.—Òwe 27:17.