ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “WÀÁSÙ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ, WÀ LẸ́NU RẸ̀ NÍ KÁNJÚKÁNJÚ.”—2 TÍM. 4:2.
Máa Lo Àǹfààní Tó O Bá Ní Láti Tan Ìhìn Rere Ìjọba Náà Kálẹ̀!
1. Kí ni àpẹẹrẹ Dáfídì kọ́ wa?
1 Dáfídì Ọba kò jẹ́ kí ìṣòro tó ní sọ ọ́ dẹni tí kò mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó wu Dáfídì láti kọ́ ilé fún Jèhófà. Àmọ́, nígbà tí Jèhófà kò gbà á láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Dáfídì tún èrò pa tó sì ṣètò àwọn ohun tí Sólómọ́nì nílò láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Ọba 8:17-19; 1 Kíró. 29:3-9) Kàkà kí Dáfídì máa ronú lórí ohun tí kò lè ṣe, ńṣe ló gbájú mọ́ ohun tó lè ṣe. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì bá a ṣe ń ro onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà máa tan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀?
2. Àyẹ̀wò ara ẹni wo ló yẹ ká ṣe?
2 Ṣe Ohun Tó O Bá Lè Ṣe: Ọ̀pọ̀ ti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. (Mát. 6:22) Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀? Bí o bá ṣàyẹ̀wò ipò rẹ, tó o sì fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà, wàá rí i pé “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” ti ṣí sílẹ̀ fún ọ. Torí náà, ṣe ni kó o lo àǹfààní tó o ní yẹn!—1 Kọ́r. 16:8, 9.
3. Àwọn àǹfààní wo ló lè ṣí sílẹ̀ fún wa láti wàásù bí a kò bá lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?
3 Tó bá jẹ́ pé ipò rẹ kò gbà ọ́ láyè láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ńkọ́? Má ṣe gbójú fo àwọn àǹfààní míì tó lè ṣí sílẹ̀ fún ọ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o pàdé àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́rìí lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ, ṣé wàá lo àǹfààní yìí láti wàásù fún wọn nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀? Tó bá sì jẹ́ pé àìlera ń bá ọ fínra, ǹjẹ́ o lè lo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fún àwọn tó ń tọ́jú rẹ? Má ṣe gbàgbé pé ètò wà fún àwọn tí kò lágbára láti ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bóyá nítorí ọjọ́ orí tàbí àìlera ara tó le gan-an láti máa ròyìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lóṣooṣù. Tó o bá ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ, rí i dájú pé o kọ àkókò tí o lò nígbà tó o jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, títí kan àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó o fi sóde, tó fi mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi àti ti àpéjọ àgbègbè. Ó máa yà ọ́ lẹ́nu láti mọ bí àkókò tó o fi jẹ́rìí ṣe pọ̀ tó bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tó nǹkan lójú rẹ nígbà yẹn.
4. Kí lo pinnu láti máa ṣe?
4 Ipò yòówù ká wà, ẹ jẹ́ ká máa lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀. A ó lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ayọ̀ tó wà nínú mímọ̀ pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nítorí Ìjọba náà.—Máàkù 14:8; Lúùkù 21:2-4.