Bí A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Wa Wọ Àwọn Tí À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́kàn
1. Ipa wo ni ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní lórí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?
1 Ọ̀rọ̀ Jésù Kristi máa ń wọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí Jésù ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, ńṣe ni ọkàn wọn bẹ̀rẹ̀ sí “jó fòfò” lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 24:32) Téèyàn bá máa jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá. Torí náà, báwo la ṣe lè ru ọkàn àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sókè kí wọ́n lè ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn?—Róòmù 6:17.
2. Báwo ni lílo ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ àwọn èèyàn lọ́kàn?
2 Máa Lo Ọgbọ́n àti Ìfòyemọ̀: Ọ̀pọ̀ ni kò ní yí padà tá a bá sọ ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ fún wọn. Kódà, wọ́n lè má fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa mọ́ tá a bá ń fi ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tú àṣírí àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Kí ọ̀rọ̀ wa tó lè wọ ẹnì kan lọ́kàn, ó yẹ ká kọ́kọ́ fi òye mọ ìdí tó fi gba àwọn ohun kan gbọ́ àti ohun tó mú kó ṣe àwọn nǹkan kan. Tá a bá fọgbọ́n bi í ní àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó sọ tọkàn rẹ̀ fún wa, èyí á jẹ́ ká lè mọ ohun tó ń rò. (Òwe 20:5) Ìgbà tá a bá lo ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ni ohun tá a kà fún wọn látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Torí náà, ó yẹ ká fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, ká sì máa ní sùúrù fún wọn. (Òwe 25:15) Ká máa rántí pé ìtẹ̀síwájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nípa tẹ̀mí ò rí bákan náà. Ká ní sùúrù kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè nípa lórí bí ẹni náà ṣe ń ronú àti àwọn ohun tó ń ṣe.—Máàkù 4:26-29.
3. Báwo la ṣe lè ran àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ rere?
3 Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lé Ní Àwọn Ànímọ́ Rere: A lè lo àwọn àyọkà inú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìwà rere àti ìfẹ́ Jèhófà láti fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa kí àwọn náà lè ní àwọn ànímọ́ rere. A lè lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 139:1-4 tàbí Lúùkù 12:6, 7 láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí Ọlọ́run ṣe dìídì nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tó. Tí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá lè ní ẹ̀mí ìmọrírì fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wọn, ìfẹ́ àti ìfọkànsìn wọn sí Ọlọ́run á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. (Róòmù 5:6-8; 1 Jòh. 4:19) Bákan náà, tí wọ́n bá mọ̀ pé ohun táwọn bá ṣe lè mú inú Jèhófà dùn tàbí bà á nínú jẹ́, èyí á mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó fẹ́, kí wọ́n sì máa bọlá fún un.—Sm. 78:40, 41; Òwe 23:15.
4. Báwo la ṣe lè ran àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ lọ́nà tí wọ́n á fi lè ṣèpinnu tó tọ́ fúnra wọn?
4 Jèhófà kò fipá mú ẹnikẹ́ni láti pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń rọ àwọn èèyàn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan pé kí wọ́n jẹ́ onígbọràn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí ọgbọ́n tó wà nínú títẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀. (Aísá. 48:17, 18) Àpẹẹrẹ Jèhófà là ń tẹ̀ lé tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí wọ́n á fi lè ṣèpinnu tó tọ́ fúnra wọn. Tó bá dá àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lójú pé ó yẹ kí wọ́n ṣe ìyípadà nígbèésí ayé wọn, ó dájú pé ìyípadà tó máa wà pẹ́ títí ni wọ́n á ṣe. (Róòmù 12:2) Èyí á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.”—Òwe 17:3.