Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Ní ọ̀pọ̀ ibi tí ogun bá ti jà, ńṣe làwọn tó ń bá ara wọn jà máa ń rò pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn. Ṣé ẹ̀yin náà rò pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn tó ń jagun? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Ilé ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi fọwọ́ sí ogun láyé àtijọ́ àti bó ṣe máa fòpin sí i títí gbére.” Ka Sáàmù 46:9 kó o sì fún un ní ìwé ìròyìn náà.
Ji! November–December
“Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé owó la fi ń lo ilé ayé. Ṣé o rò pé ó léwu tí èèyàn bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó gba òun lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìkìlọ̀ Bíbélì yìí. [Ka 1 Tímótì 6:9.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa owó.”