Ìmúrasílẹ̀ Tó Yẹ Ká Ṣe Ká Lè Kọ́ni Lọ́nà Tó Já Fáfá
Ó kéré tán, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n bi Jésù ní ìbéèrè kan náà nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àmọ́ ó dáhùn ìbéèrè náà lọ́nà tó bá ipò àwọn tó bi í ní ìbéèrè náà mu. (Lúùkù 10:25-28; 18:18-20) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ Bíbélì àti ìwé tá a fi ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ó yẹ ká máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ ká tó lọ darí rẹ̀, ká sì ronú nípa ibi tí òye akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ. Àwọn kókó wo ló lè má tètè yé akẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí tí kò fara mọ́? Èwo nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí ló yẹ ká kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́? Ìpínrọ̀ mélòó ló yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́? A lè múra àpèjúwe kan, àlàyé tá a máa ṣe tàbí àwọn ìbéèrè tá a máa bi akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ èyí táá jẹ́ kó lóye ohun tó ń kọ́ dáadáa. Láfikún sí i, torí pé Jèhófà ló máa jẹ́ kí irúgbìn òtítọ́ tá a fún sínú ọkàn àwọn èèyàn dàgbà, ó yẹ ká bẹ̀ ẹ́ pé kó fi ìbùkún sí ìmúrasílẹ̀ tá a ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kó ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, kó sì bù kún ìsapá wa láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.—1 Kọ́r. 3:6; Ják. 1:5.