MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
MÚ KÍ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ SUNWỌ̀N SÍ I Máa Fún Àwọn Tó Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa Níṣìírí Láti Wá sí Ìpàdé
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Láwọn ìpàdé wa, a máa ń ‘kọ orin sí Jèhófà’ a sì tún máa ń ‘fi ìyìn fún un.’ (Sm 149:1) A máa ń kọ́ bá a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láwọn ìpàdé wa. (Sm 143:10) Àwọn tó bá fìfẹ́ hàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sábà máa ń tẹ̀ síwájú gan-an tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé wa.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó pè wọ́n wá sí ìpàdé. Má ṣe dúró dìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀.—Iṣi 22:17
Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń ṣe ìpàdé fún ẹni tó fìfẹ́ hàn náà, kó o sì jẹ́ kó mọ ohun tá a máa gbádùn nípàdé tó ń bọ̀. Àwọn nǹkan tó o lè lò rèé: Ìwé ìkésíni sí àwọn ìpàdé ìjọ, fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?, àti ẹ̀kọ́ 5 àti 7 nínú ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣé ẹni náà fẹ́ kí ẹnì kan fi mọ́tò tàbí ohun ìrìnnà míì gbé òun lọ sí ìpàdé? Ṣé o lè bá a yan aṣọ tó bójú mu? Jókòó tì í ní ìpàdé, kẹ́ ẹ sì jọ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a bá ń lò. Fi ojú rẹ̀ mọ àwọn míì nínú ìjọ