Àwọn akéde kan ń pe àwọn èèyàn wá sí ìpàdé ní Cook Islands
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Ṣé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́?
Ka Bíbélì: Sm 103:20
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn áńgẹ́lì àti ohun tí wọ́n ń ṣe fún wa báyìí.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o rò pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ta ko Bíbélì?
Ka Bíbélì: Ais 40:22
Òtítọ́: Gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì pátá ló péye.
ÌWÉ ÌKÉSÍNI SÍ ÀWỌN ÌPÀDÉ ÌJỌ (inv)
Fi ìwé lọni: Mo fẹ́ pè yín láti wá gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì, ọ̀fẹ́ ni o. Ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yín la ti máa ṣe é. [Fún un ní ìwé ìkésíni, sọ àkókò àti àdírẹ́sì ibi tẹ́ ẹ ti máa ń ṣe ìpàdé ní òpin ọ̀sẹ̀, kó o sì sọ àkòrí àsọyé tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn.]
Béèrè ìbéèrè: Ṣé ẹ ti lọ sí ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí? [Tó bá ṣeé ṣe, fi fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án.]
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.