Ọlọ́run Ìfẹ́ Máa Fún Ẹ Ní Ọ̀pọ̀ Ohun Rere
Ṣó wù ẹ́ kí ogun, ìwà ọ̀daràn àti ìjà dópin láyé?
Ṣó wù ẹ́ kí àìsàn, ìyà àti ikú dópin?
Ṣó wù ẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú àti ìṣòro?
Ṣó wù ẹ́ kó o máa gbé ibi tí kò sí àjálù bí ìjì líle tàbí àkúnya omi?
Ẹlẹ́dàá wa tó dá ayé tó rẹwà yìí nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ó sì ṣèlérí pé aráyé máa gbé nínú ayọ̀ àti àlàáfíà títí láé. Èyí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o fiyè sí ohun tá a fẹ́ sọ nípa àwọn nǹkan yìí:
Ohun tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa
Ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ohun táwọn wòlíì sọ nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣèlérí
Ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀ nísinsìnyí, táá sì tún jẹ́ ká gba ọ̀pọ̀ ohun rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú
Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.