ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 November ojú ìwé 5
  • Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Olùkọ́ Ńlá Náà Ni Kó O Máa Tẹ̀ Lé Bó O Bá Ń Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni La Óò Máa Fi Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 November ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

Ohun tó wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? àti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni jọra gan-an. Ọ̀nà kan náà la gbà to àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ méjèèjì. Àmọ́, ọ̀nà tó rọrùn láti lóye la gbà ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa. Torí àwọn tó ṣeé ṣe kó ṣòro fún láti lóye ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ṣe ṣe é. Dípò àfikún tó wà lẹ́yìn ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, àfikún àlàyé la lò nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa láti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Kò sí àwọn ìbéèrè tó máa ń wà níbẹ̀rẹ̀ àkòrí kọ̀ọ̀kan àti àpótí àtúnyẹ̀wò nínú ìwé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ṣe àkópọ̀ ṣókí ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan láti fi ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tá a jíròrò ní orí náà. Bíi ti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, a lè fi ìwé Bíbélì Kọ́ Wa lọ àwọn èèyàn nígbàkigbà, kódà bí kì í bá ṣe òun là ń lò lóṣù yẹn. Báwo la ṣe lè lo àwọn apá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Àkópọ̀ ṣókí nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa

ÀTÚNYẸ̀WÒ: Bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, lẹ́yìn tá a bá ti ka ìpínrọ̀ kan tán, máa ń gbádùn mọ́ àwọn kan. Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ èdè wa dáadáa tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà ńkọ́? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, o lè pinnu láti lo ìwé Bíbélì Kọ́ Wa. O wá lè lo apá tó ṣe àkópọ̀ ohun tó wà ní orí kọ̀ọ̀kan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì gba akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti ka orí náà láyè ara rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè má lò ju ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ láti fi òtítọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́. Níwọ̀n bí àtúnyẹ̀wò yìí kò ti ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nínú, ó máa dáa kí olùkọ́ múra sílẹ̀ dáadáa, kó ronú nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà nílò. Tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹ ka ìpínrọ̀ náà lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ lè lo apá yìí láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ kọ́.

Àfikún àlàyé nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa

ÀFIKÚN ÀLÀYÉ: Bí àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹ̀kọ́ tá a jíròrò nínú ìwé náà ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn nínú orí kọ̀ọ̀kan la ṣe tò wọ́n sínú àfikún àlàyé. Olùkọ́ lè pinnu bóyá kí òun jíròrò àfikún àlàyé tó wà nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń lọ lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́