MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Máa Ń Dárí Ji Ara Rẹ?
Ó sábà máa ń ṣòro fún wa láti dárí ji ara wa, tá a bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn, tó sì jẹ́ pé Jèhófà ti dárí jì wá. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nínú àsọyé kan tó ní fídíò nínú nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà!” tá a ṣe lọ́dún 2016. Wo fídíò náà lórí JW Library lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ṣe pẹ́ tó kí wọ́n tó gba Ṣadé pa dà?
Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ni àwọn alàgbà kà fún Ṣadé, báwo ló ṣe ràn án lọ́wọ́?
Báwo ni àwọn ará ìjọ ṣe ṣe sí Ṣadé nígbà tí wọ́n gbà á pa dà?
Àwọn èrò wo ni Ṣadé máa ń ní, báwo ni bàbá rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́?