MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní—Ìgboyà
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:
A gbọ́dọ̀ ní ìgboyà ká tó lè wàásù. —Iṣe 5:27-29, 41, 42
Ìpọ́njú ńlá máa fi hàn bóyá a ní ìgboyà.—Mt 24:15-21
Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń yọrí sí wàhálà. —Jer 38:17-20; 39:4-7
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.—Ẹk 14:13
Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ìgboyà. —Iṣe 4:29, 31
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm 118:6
What fears do I need to overcome in my ministry?
WO FÍDÍÒ NÁÀ, YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ BA ÌDÚRÓṢINṢIN RẸ JẸ́—ÌBẸ̀RÙ ÈÈYÀN, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ní ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Ohun méjì tó yàtọ̀ síra wo ló wà nínú Òwe 29:25?
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa fi ìgboyà ṣe ìfẹ́ Jèhófà nísinsìnyí?