ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 October ojú ìwé 7
  • Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣiṣe Iṣiro Lori Ìlò Owó-Àkànlò Kristi
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Jẹ́ Kí Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní Máa Múnú Rẹ Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 October ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!

Ẹ̀mí ṣeyebíye gan-an. Àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́ máa ń fi hàn bóyá a mọyì ẹ̀mí wa tàbí a ò mọyì rẹ̀. Àwa èèyàn Jèhófà máa ń sapá láti rí i pé a lo àwọn ẹ̀bùn wa láti yin Jèhófà àti láti bọlá fún un, torí pé òun ni Orísun Ìyè. (Sm 36:9; Iṣi 4:11) Àmọ́ tá ò bá múra, nítorí kòókòó-jàn-án-jàn-án inú ayé burúkú yìí, a lè dẹni tí kò fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. (Mk 4:​18, 19) Ó wá yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ohun tó dára jù lọ ni mò ń fún Jèhófà? (Ho 14:⁠2) Ṣé iṣẹ́ mi kò ti fẹ́ gba ìjọsìn Jèhófà mọ́ mi lọ́wọ́? Kí ni àwọn nǹkan tẹ̀mí tí mo pinnu láti ṣe? Báwo ni mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjísẹ́ mi?’ Tó o bá rí i pé o nílò àtúnṣe, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé tá a bá ń fi ayé wa yin Jèhófà lójoojúmọ́, a máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì lóyin!​—Sm 61:8.

Edgardo Franco performs on stage; Edgardo Franco in the field ministry

Ta ni ìwọ ń lo ẹ̀bùn rẹ fún?

WO FÍDÍÒ NÁÀ LO Ẹ̀BÙN Ẹ FÚN IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti lo àwọn ẹ̀bùn wa fún ayé Sátánì? (1Jo 2:17)

  • Tá a bá fún Jèhófà ní ohun tó dára jù, àwọn ìbùkún wo la máa rí?

  • Àwọn ọ̀nà míì wo lo lè gbà lo ẹ̀bùn rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́?

ÀBÁ FÚN ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ:

  • Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Jèhófà, bóyá to jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé àwọn nǹkan wo ló yááfì kó lè fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ? Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún rẹ̀?

  • Lọ sí Tẹlifíṣọ̀n JW, wo abẹ́ ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ ÀTI ÌRÍRÍ. Wàá gbọ́ ìrírí tó ń mú orí ẹni wú láti ẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti fi ayé wọn jìn fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́