ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 4-5
Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù
Sátánì máa ń gbìyànjú láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ nípa mímú ká máa ro èròkérò. Ó máa ń lo ọgbọ́n yìí fún wa lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ sí àti ipò tá a wà.
Ohun ìjà tó lágbára wo ni Jésù lò láti fi borí àwọn ìdẹwò mẹ́ta tí Sátánì sábà máa ń lò? (Heb 4:12; 1Jo 2:15, 16) Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?