ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 August ojú ìwé 8
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
    Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Lèrò Rẹ?
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 August ojú ìwé 8
Arákùnrin kan ń lo káàdì ìkànnì jw.org

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ló ń darí àwọn èèyàn sí ìkànnì jw.org. Olórí ìdí tá a fi ṣe káàdì ìkànnì jw.org àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? ni láti darí àwọn èèyàn sí ìkànnì wa. O lè lo ìkànnì jw.org láti fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni pé ká fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí wọ́n fi ń gba lẹ́tà lórí Kọ̀ǹpútà tàbí ká fi ìlujá ránṣẹ́, èyí sì máa gbéṣẹ́ nígbà tá a bá ń wàásù fún ẹnì kan tí kò gbọ́ èdè wa. Láfikún sí i, àwọn èèyàn lè béèrè àwọn ìbéèrè tí kò sí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá mọ bá a ṣe lè lo ìkànnì náà, ó máa jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ sèso rere.

BÁ A ṢE LÈ LO:

  • Ẹnì kan ń lo káàdì ìkànnì láti lọ sórí jw.org

    Abala “Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ”. Ká sọ pé ò ń wàásù fún òbí kan tó fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọmọ títọ́. Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÌDÍLÉ.

  • Abala “ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE”. Ká sọ pé ò ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà níléèwé, tó o sì fẹ́ jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè pẹ̀lú ọmọ iléèwé rẹ. Lọ sí ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ.

  • Abala “NÍPA WA”. Ká sọ pé ò ń wàásù fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, tẹ́ni náà sì fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa ohun tá a gbà gbọ́. Lọ sí NÍPA WA > ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ.

WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁ A ṢE LÈ LO ÌKÀNNÌ JW.ORG, LẸ́YÌN NÁÀ WÁ IBI TÓ O LÈ LỌ LÁTI ṢÈRÀNWỌ́ FÚN:

  • ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà

  • ẹni tí àjálù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí

  • arákùnrin tàbí arábìnrin tó ti di aláìṣiṣẹ́ mọ́

  • ẹni tí a ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ tó fẹ́ mọ bá a ṣe ń rówó ṣe iṣẹ́ ìwàásù

  • ẹni tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, tó sì fẹ́ mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní orílẹ̀-èdè rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́