ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 20-21
“Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn apẹja tó ń rí ẹja pa dáadáa máa ń jẹ́ onísùúrù, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì ṣe tán láti fara da ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n bàa lè rí èrè púpọ̀. (w12 8/1 18-20) Àwọn ànímọ́ yìí máa ran Pétérù lọ́wọ́ bó ṣe ń ṣiṣẹ́ apẹja èèyàn. Àmọ́, Pétérù ní láti pinnu ohun tó máa fi sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀, bóyá á máa bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nípa tẹ̀mí tàbí iṣẹ́ apẹja tó mọ̀ ọ́ ṣe dáadáa ló máa gbájú mọ́.
Àwọn àyípadà wo lo ti ṣe kó o lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́?